Minisita fọrọ awọn oṣiṣẹ, Ngige, loun ko dupo aarẹ mọ o

Jọkẹ Amọri

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Minisita to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ nilẹ wa, Dokita Chris Ngige, kede ninu iwe kan to kọ, to si buwọ lu funra rẹ, pe oun ti yi ipinnu oun lati dupo aarẹ pada, oun si ti ṣetan lati maa ba iṣẹ minisita ti Buhari yan oun si lọ.
Ọkunrin to ti gba fọọmu, to si ti fifẹ han lati dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC yii sọ pe lẹyin ti oun ti ṣe ipade pẹlu Aarẹ Buhari, ti oun si ti fi ọrọ lọ awọn mọlẹbi oun, agbegbe oṣelu ti oun ti wa, awọn ọrẹ ati ololufẹ oun loun ṣe ipinnu naa.
O fi kun un pe oun ti sọ ipinnu oun yii di mimọ fun Aarẹ Buhari ati Akọwe ijọba apapọ.
Ninu lẹta naa lo ti sọ pe lẹyin ti oun ti ṣepade ọlọkan-o-jọkan pẹlu awọn tọrọ kan, oun ko ni i kopa ninu idibo abẹle abi igbesẹ yiyan aarẹ lasiko eto idibo naa ti yoo waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, yii. Ngige ni oun ṣe ipinnu yii fun ifẹ orileede ati ki oun le raaye kọju mọ iṣẹ minisita ti oun n ṣe, ati lati ran ijọba Aarẹ Buhari lọwọ lati ṣaṣeyọri pẹlu bi saa ijọba wọn ti fẹẹ tẹnu bopo. O ni awọn mọlẹbi oun paapaa wa ninu oun ti oun ro ti oun fi ṣe ipinnu yii.
‘‘Mo n fi asiko yii sọ fun awọn alatilẹyin mi, awọn oloṣelu ẹgbẹ mi kaakiri agbegbe ti mo ti wa, awọn ọmọ ẹgbẹ mi pe mi o dije mọ, ipinnu yii si leke ohun gbogbo ti mo ti sọ ṣaaju lori erongba mi lati dupo aarẹ.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Ngige fi erongba rẹ lati dupo aarẹ han, bẹẹ lo si gba fọọmu ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni miliọnu lọna ọgọrun-un lati fi dupo naa.

Leave a Reply