Mọṣuari ni Roheem Adedoyin sọ fun wa pe oun n gbe oku Timothy lọ – Kazeem

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kazeem Oyetunde, to n tun awọn nnksn eelo omi ẹrọ ile ṣe (Plumber), ninu ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, ti sọ fun kootu pe ṣe ni wọn sọ fun oun ati manija otẹẹli naa, Adeniyi Aderọgba, pe wọn n gbe oku Timothy lọ si mọsuari lọjọ ti wọn ju oku rẹ sinu igbo.
Nigba ti agbẹjọro olupẹjọ n takoto ibeere si Kazeem lori iku Timothy, akẹkọọ Fasiti Ifẹ to ku si otẹẹli naa loṣu Kọkanla, ọdun to kọja, lo ni oun beere lọwọ Roheem to jẹ alamoojuto otẹẹli naa nigba to mori le ọna ibi ti wọn ju oku naa si.

O ni oun ati Aderọgba tẹle Roheem lọ si yara 305 ti Timothy wa, awọn si ba a pe o ti ku. O ni o kuro lọdọ awọn, o si sọ pe oun fẹẹ lọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.
Kazeem fi kun ọrọ rẹ pe irọlẹ ọjọ yẹn ni Roheem too de, nigba ti awọn si beere idi to fi pẹ, o ni awọn ọlọpaa sọ pe ki oun kọ akọsilẹ iṣẹlẹ naa ati pe wọn ti ni ki oun gbe oku naa lọ si mọṣuari.
O ni oun ati Aderọgba lawọn kun Roheem lọwọ lati gbe oku naa sinu hilux van ti Roheem wa, ṣugbọn dipo ko gba mọṣuari lọ, ṣe lo mori le ọna Ẹdẹ Road, nigba ti awọn si beere idi ti ko fi gbe oku naa lọ si mọsuari mọ, o ni ẹru awọn ọlọpaa lo n ba oun.

O ni Roheem nikan lo gbe oku naa jade ninu mọto lọ si ẹgbẹ ibi to ju u si, ati pe oun ko ba ẹnikẹni bura tabi lẹdi apo pọ mọ ẹnikẹni nipa iku Timothy.
Bakan naa ni alakooso awọn oṣiṣẹ alaabo ni otẹẹli naa, Lawrence Oluwọle, sọ pe ẹnu iṣẹ ti oun ṣe lotẹẹli naa lọjọ naa ni yiyẹ akọsilẹ iye yara ti awọn alejo ko gba wo ninu iwe akọsilẹ akọwe (receptionist), o ni oun ko yẹ yara Timothy wo, niwọn igba ti akọsilẹ ti sọ pe alejo wa nibẹ, bẹẹ ni oun ko si da a mọ.

Leave a Reply