Mo ṣekilọ nipa ijọba eṣu to wa lode yii lọdun 2015, ṣugbọn wọn o gbọ – Oyedepo

Faith Adebọla, Eko

Gbajugbaju ajihinrere ati oludasilẹ ijọ Living Faith Church Worldwide, tawọn eeyan mọ si Winners, Biṣọọpu David Oyedepo, ti ṣapejuwe iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari bii ijọba eṣu, ijọba buruku to ko awọn ọmọ Naijiria pada sinu aginju nla, o loun si ṣekilọ gidi ṣaaju pe bijọba naa ṣe maa ri ree, ṣugbọn ọpọ eeyan lo kọti ọgbọnyin si ikilọ ọhun.

Ninu iwaasu rẹ lọjọ Aiku, Sannde yii, eyi to waye ni olu-ileejọsin ọhun, to wa ni Cannanland, Ọta, nipinlẹ Ogun, lojiṣẹ Oluwa naa ti sọrọ yii.

Oyedepo, nigba to n sọrọ nipa agbara asọtẹlẹ Ọlọrun ati bo ṣe yẹ kawọn eeyan maa kọbiara si ikilọ, o ni:

“Mo jẹ ọkan lara awọn eeyan ti Oluwa fun lanfaani lati mọ ohun to maa ṣẹlẹ lọjọ iwaju, Ọlọrun si maa n fi han mi ṣaaju ko too waye.

Ọpọ eeyan lo binu si mi nigba ti mo n sọrọ nipa ijọba eṣu yii nigba yẹn, mo sọ forileede yii, mo ni ‘Haa, inu wahala la fẹẹ tọrun bọ lọdun 2015 yii o’, ṣe wahala ni ki n pe e abi agbako nla? Agbako gidi ni.

Tori mo ti ri iwa ika tawọn ika ẹda kan fẹẹ fi tipatipa mu ba ilẹ wa. Ẹ waa wo ipo ti a wa bayii, ko si itọsọna kankan, ko si itẹsiwaju kan, gbogbo ẹ waa lọju-pọ pata.

Nigba ti wolii ba n sọrọ, ero Ọlọrun lọ n sọ jade yẹn. Ṣugbọn oju gbogbo wa ti ri abajade ẹ bayii.

Emi kọ ni mo maa ba yin gba ọrọ aṣọtẹlẹ gbọ, ẹni kọọkan lo gbọdọ gba a gbọ, lati ri imuṣẹ ẹ.”

Bẹẹ ni Oyedepo kede nipa ijọba to wa lode yii, ninu iwaasu rẹ

Leave a Reply