Mo fẹ ki awọn agbofinro wa ọlọpaa to pa ọmọ mi, ki wọn si san biliọnu marun-un naira fun ẹbi mi – Iya Idris

Florence Babaṣọla

Iya to bi Idris Ajibọla ti awọn ọlọpaa kan le titi to fi ku ninu asidẹnti ọkọ lọdun to kọja niluu Oṣogbo, Arabinrin Titilayọ Ajibọla, ti sọ pe ohun meji ti oun fẹ lọdọ awọn ọlọpaa ni ki wọn ṣawari awọn arufin naa, ki wọn si san owo gba-ma-binu fun mọlẹbi oun.

Idris ni ikọ alajumọṣe awọn agbofinro (JTF) le mọto toun atawọn ọrẹ rẹ gbe wa sileetaja nla Justrite, niluu Oṣogbo, lọdun to kọja, titi ti ọkọ naa fi fori sọ opo ina onisimẹnti, ti ọkọ naa si gbokiti, loju-ẹsẹ ni Idris ku, awọn mẹta yooku si fara pa yanna-yanna.

Lasiko ti obinrin naa fara han niwaju igbimọ to n gbọ ẹsun iwa ọdaran awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lo ṣalaye pe oun mọ pe ṣe nileeṣẹ ọlọpaa n gbe awọn ọlọpaa ti wọn ṣiṣẹ naa pamọ.

O sọ pe lọna keji, mọlẹbi naa n beere biliọnu marun-un naira lati le jẹ ki awọn ọlọpaa ni imọlara iwa buburu ti wọn hu pẹlu bi wọn ṣe da idile naa loro nla nipasẹ iku Idris.

Obinrin yii fi kun ọrọ rẹ pe loootọ owo naa ko to ẹmi Idris, ṣugbọn to ba jẹ pe ọmọ naa wa laye, yoo ṣe ohun to pọ ju owo naa lọ fun idile naa, idi niyẹn ti wọn ṣe pinnu lati kọ awọn ọlọpaa lẹkọọ lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹjọro awọn olupẹjọ, Barisita Kanmi Ajibọla, ṣalaye pe owo gba-ma-binu naa wa lati kọ ileeṣẹ ọlọpaa atawọn agbofinro ti wọn huwa naa lọgbọn.

Ajibọla fi aidunnu rẹ han si bi awọn to yẹ ki wọn maa daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu ṣe di ẹrujẹjẹ saarin ilu, o ni ti idajọ ododo ba le wa lori iku Idris, o di dandan ki wọn kọwọ ọmọ wọn baṣọ.

O ni idajọ ti igbimọ naa ba gbe kalẹ lori ẹjọ yii ni yoo sọ igbesẹ to ku ti awọn olupẹjọ yoo gbe nitori wọn ti pinnu lati ba ẹjọ naa debi to lapẹẹrẹ, idi niyẹn ti wọn fi fun kọmisanna ọlọpaa Ọṣun lorukọ awọn ọlọpaa meji ti wọn fura si, ki iwadii le bẹrẹ latọdọ wọn.

Lẹyin gbogbo atotonu yii ni igbimọ naa sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, ọdun yii.

Leave a Reply