Mo gbọdọ lo awọn iriri ti mo ti ni, oye mi, ati anfaani ti mo ni fun Naijiria ati ẹyin ọmọ Naijiria

Gbenga Amos

Nnkan bii ọdun meje sẹyin ni mo ti n sin gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ bọ, pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari to jẹ ọmọ Naijiria tootọ, iranṣẹ orileede yii lasiko ogun ati alaafia, ọkunrin olootọ ati aduro ṣinṣin.
Asiko ti nnkan le koko ju lọ ninu itan orileede wa la jọ ṣiṣẹ papọ loootọ, ṣugbọn a o yẹsẹ lori ipese aabo, ipese ohun amayedẹrun ati riro eto ọrọ-aje wa lagbara.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin Naijiria, ọdun to n bọ ni saa iṣejọba waa yoo tẹnu bepo.
Laarin ọdun meje yii, mo ti sin ni ọpọ ẹka, titi kan ṣiṣoju fun orileede wa lawọn ijooko pataki kan, gẹgẹ bi aarẹ ba ṣe yanṣẹ fun mi. Ko si ijọba ibilẹ kan lorileede wa ti mi o de ri. Mo ti de awọn ọja, awọn ileeṣẹ nla nla, awọn ileewe, ati oko. Mo ti lọ saarin awọn agbẹ, awọn awakusa, ati awọn to n pese epo rọbi, lagbegbe Delta ni o, ni Kebbi, Enugu, Borno, Rivers, Plateau ati Ondo, ati kaakiri awọn ipinlẹ yika orileede wa, gbigbọ ibẹ ni mo ti tẹti si awọn eeyan pẹlu iriri oriṣiiriṣii ti wọn ni, ati gbogbo nnkan to jẹ idaniyan wọn.
Mo ti ṣabẹwo sawọn ọmoogun wa lagbegbe Ariwa/Ila-Oorun, atawọn arakunrin arabinrin wa ti wọn wa lawọn ibudo ogunlende gbogbo. Mo ti mọ bi oju ṣe n pọn wọn to, ti wọn si n daamu latari ija, akọlu awọn afẹmiṣofo, iṣẹlẹ omiyale, ti ina ọmọ ọrara, ati awọn ajalu mi-in to ṣẹlẹ si wọn. Mo ti ṣabẹwo sile awọn eeyan to jẹ mẹkunnu kaakiri orileede yii. Mo ti jokoo pẹlu awọn olokoowo onimọ-ẹrọ l’Ekoo, l’Edo ati ni Kaduna, ati pẹlu awọn olorin atawọn oṣere tiata ilẹ wa l’Ekoo, l’Onitsha ati Kano. Mo ti ba awọn olokoowo kereje atawọn aladaa-nla sọrọ.
Gbogbo bi nnkan ṣe n lọ fun wọn si ni mo ri, titi kan ireti wọn, ifẹ-ọkan wọn, atawọn ohun to n ba wọn lẹru, mo si gbagbọ pe ireti ati erongba wọn yẹn, ni ipilẹ fun orileede Naijiria rere ti gbogbo wa fẹ.
Mo gbagbọ pe, idi pataki ti Ọlọrun Olodumare fi jẹ ki n ni awọn iriri, oye ati anfaani ti mo ni niyẹn, pe ki n le lo o fun orileede yii atawọn eeyan inu rẹ.
Tori idi yii, lonii, mo fi tirẹlẹ tirẹlẹ kede erongba mi lati dije fun ipo aarẹ orileede Naijiria, labẹ asia ẹgbẹ wa, ẹgbẹ nla, All Progressives Congress. Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun ati atilẹyin ẹyin eeyan, tẹ ẹ ba fun mi lanfaani yii, mo gbagbọ pe lakọọkọ, a gbọdọ pari awọn ohun ta a ti dawọ le bii:
• Mimu ayipada ọtun ba eto aabo ati ọgbọn-inu
• Mimu igba ọtun ba ẹka idajọ wa, pẹlu owo-oṣu to yẹ, ka si ṣetọju awọn eleto idajọ wa bo ṣe tọ.
• Mimu ki idajọ ododo wa fun gbogbo eeyan, ka si bọwọ fofin.
• Ipese ohun amayedẹrun gbọdọ tẹsiwaju, paapaa lẹka ipese ina ẹlẹntiriiki ati agbara, awọn ọna, reluwee, ati ẹrọ ayelujara.
• Ipese ayika to maa mu ki okoowo gberu daadaa
• Mimu ayipada ati itẹsiwaju ba iṣẹ agbẹ, pẹlu ilo ati ilana ẹrọ igbalode, ti ire oko yoo fi maa dori tabili awọn araalu pẹlu irọrun.
• Riri i daju pe awọn ẹka ileeṣẹ ọba gbogbo ṣiṣẹ fun ire awọn olokoowo bo ṣe yẹ.
• Lilo imọ ẹrọ lati pese iṣẹ yanturu fawọn araalu
• Ṣiṣonigbọwọ fawọn eto leṣẹẹlugbẹẹ lati le pese iranwọ gidi fawọn eeyan.
• Ṣiṣe aṣepari ileri ta a ṣe lati bọ aṣọ oṣi kuro lọrun ọgọrun-un miliọnu araalu, ki ọdun mẹwaa too pe
• Riri i daju pe gbogbo ọmọ Naijiria, lọkunrin lobinrin, ri ileewe lọ.
• Mimu atunto ba eto ẹkọ wa lati le koju ipenija asiko yii ati tọjọ iwaju
• Riro awọn ijọba ibilẹ ati tipinlẹ lagbara ki wọn le ṣojuṣe wọn bo ṣe tọ.
Lakootan, lajori isapa wa maa da lori ipese iṣẹ ati anfaani fawọn ọdọ wa.
Ni bayii, pẹlu itara ati ọwọ ni mo fi rawọ ẹbẹ sẹyin ọmọ Naijiria ẹlẹgbẹ mi nibi gbogbo lorileede yii, ati lẹyin odi, atọmọde atagba, lọkunrin lobinrin, pe kẹ ẹ gbaruku ti mi, ka jọ rinrin-ajo to wa niwaju wa yii.
Ta a ba jọ rin in, pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun, ala rere ta a ni nipa Naijiria to wu wa, maa to wa lọwọ lọdun diẹ si i.
Lori ipilẹ tawọn aṣaaju wa ti fi lelẹ naa la maa mọle si, a si maa ni lati gbesẹ kanmọ kanmọ ninu erongba wa ati ifarada wa, ki ala wa nipa orileede ti nnkan ti rọṣọmu, to fiiyan lọkan balẹ, to si laabo, le wa simuuṣẹ.
Mo gbagbọ daadaa, ko si iyemeji lọkan mi, pe ọgbọn atinuda, igboya, ẹbun abimọni, ati nnkan eelo ta a nilo lati di orileede eeyan dudu to lewaju ju lọ lagbaye wa lọwọ wa. O ti tasiko, ẹ jẹ ka bi orileede ologo ti awọn iran to ṣaaju wa ti loyun ẹ tipẹtipẹ.
Ẹ jẹ ka sọ Naijiria di orileede ti ẹni to n bọ lati Nnewi maa ri ti Gusau gẹgẹ bii ọmọọya, ti obinrin Warri maa mu ti Jalingo bii arabinrin ẹ, ti ifẹ orileede wa yoo si maa jo lala bii ina lọkan awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin wa, lati Gboko titi de Yenogoa.
Orileede ti ibikibi yoowu ta a ba wa yoo jẹ ile fun kaluku, nibi ti awọn iyatọ wa, bii ẹya ati ẹsin yoo ti mu ka wa niṣọkan, dipo ipinya.
Ẹ jẹ ka sọ awọn ẹya wa di ẹya kan, ẹya Naijiria, ti kaluku wa yoo maa ba ara wa lo pẹlu ẹtọ, idajọ ododo ati ọwọ, ti gbogbo wa yoo si lanfaani kan naa lati jẹ mukudun awọn nnkan meremere t’Ọlọrun fi jinki orileede yii.
O ti tasiko bayii.
Ki Ọlọrun bukun wa, ko si pa Naijiria ati awọn eeyan inu rẹ mọ.
Emi ni, Ọjọgbọn Amofin agba Yẹmi Ọṣinbajo
Igbakeji aarẹ Naijiria.

Leave a Reply