Mo kabaamọ pe mo wa lara awọn to ṣiṣẹ fun Buhari to fi di Aarẹ- Gomina Ortom

Gbenga Amos

“Ijọba apapọ yii ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ ni gbogbo ọna, mo si n lo anfaani yii lati sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati gba pe oun ti ja orileede yii kulẹ, ko kọwe fipo silẹ, o maa niyi fun un to ba kuro nipo aarẹ Naijiria bayii.”

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom lo n fi aidunnu rẹ han bẹẹ lasiko apero pẹlu awọn oniroyin kan to waye niluu Makurdi, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu yii.

Gomina naa ni nigba toun wo kaakiri Naijiria, toun si ranti gbogbo ileri ti Buhari ṣe lọdun 2014 to n ṣepolongo ibo lati di aarẹ, niṣe loun tika abamọ bọnu pe oun wa lara awọn eeyan to ṣiṣẹ kara ki Buhari le di aarẹ, tori ko si ẹyọ kan ṣoṣo pere ninu awọn ileri naa teeyan le tọka si pe Buhari ṣe yanju daadaa.

“Bẹẹ ni, ẹ jẹ ki Buhari fipo silẹ, ko fa ijọba le igbakeji rẹ lọwọ. Aijẹ bẹẹ, orileede yii maa fẹyin balẹ laipẹ.

“Mo wa lara awọn to ṣiṣẹ kara fun Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2015, latari awọn ileri to ṣe fun wa pe toun ba di aarẹ gbogbo eeyan loun maa ṣanfaani fun, oun o si ni i role apa kan da ọkan si. Ṣugbọn lonii, kedere lo han pe Aarẹ awọn Fulani nikan ni, ojoojumọ ni agabagebe ati ojooro n waye lorileede yii.

“Mo mọ pe bo ṣe n ṣẹlẹ nipinlẹ mi ti mo n sọrọ nipa ẹ yii naa lo n ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ mi-in o, ọrọ ti ipinlẹ mi, nibi ti wọn ti yan mi gẹgẹ bii gomina lati pese iṣakoso rere to maa mu aabo ẹmi ati dukia wa, ni mo n sọ.

“Nnkan o daa rara, o si ṣe mi laaanu, mo gbadura fawọn ẹlẹgbẹ mi ati awọn eeyan ipinlẹ yooku pe ki Ọlọrun ran wa lọwọ. Ṣugbọn ọrọ adura nikan kọ, afi ka gbe igbesẹ nipa ẹ, tori ẹkọ ti mo kọ ninu Bibeli jẹ ki n mọ pe igbagbọ lai si iṣẹ, oku ni. Eeyan gbọdọ gbe igbesẹ.

Emi maa gbe igbesẹ ni temi, mo ti ba awọn eeyan mi sọrọ, mo si ti mọ nnkan ti ma a ṣe, mi o ni i sọ iyẹn ni gbangba yii. A maa gbe igbesẹ gidi, tori o ti doju ẹ bayii, o ti to gẹẹ.

A ti pariwo titi, a ti sunkun titi, aa ni i pariwo mọ. Lẹyin apero ti mo n ṣe yii, mi o tun ni i sọ fẹnikan mọ pe iye eeyan bayii ni wọn ṣekupa lawọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ wa. Iyẹn ti kọja. A maa gbe igbesẹ pato lati kun awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọwọ, ṣugbọn a o ni i gba ki eto aabo ati alaafia wa mẹhẹ mọ. O to gẹẹ, o si to gẹẹ ni mo wi yẹn.

Awọn afẹmiṣofo ni wọn le eeyan miliọnu kan aabọ ta a ko si awọn ibudo ogunlende, kuro nile wọn. Awọn ẹṣọ alaabo naa si ti sa gbogbo ipa wọn latọdun 2017, ohun to ju ọgọrun-un lara wọn lo ṣofo ẹmi.

Mo mọ pe wọn n gbiyanju gbogbo ohun to wa lagbara wọn, ṣugbọn wọn o pọ to, wọn o pọ to rara ni.”

Bẹẹ ni Othom wi.

Leave a Reply