Mo maa n jẹ ẹya ara eeyan bii nnkan ọmọkunrin, oju, ifun ati gogongo, mo si tun maa n ta a fawọn to ba fẹ-Aminu

Aminu Baba lọkunrin to jokoo yii n jẹ, ẹnu ara ẹ lo fi jẹwọ pe oun maa n jẹ ẹran eeyan, bẹẹ loun si tun maa n ta a.

Ipinlẹ Zamfara ni Aminu yii n gbe, mọto lo n ta nibi kan ti wọn n pe ni Aminchi Motors, ni Gusau.

Ṣugbọn niṣe lo kan n fiṣẹ mọto tita naa boju gẹgẹ boun funra ẹ ṣe ṣalaye, iṣẹ to n ṣe gan-an ni pe o maa n pa awọn ọmọdekunrin, o si maa n jẹ wọn, yoo si tun ta ninu ẹya ara wọn.

Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ fawọn ọlọpaa lẹyin tọwọ ba a, Aminu Baba sọ fun wọn pe oun gba awọn ọmọkunrin meji kan lati maa ba oun wa awọn ọmọdekunrin toun le pa.

O ni wọn ti ba oun wa ọmọkunrin lẹẹmeji, oun si san miliọnu kan naira fun wọn.

Aminu sọ pe, “A yọ nnkan ọmọkunrin wọn, oju, ifun ati gogongo wọn. Mo maa n jẹ awọn ẹya ara wọnyi mo dẹ maa n ta awọn mi-in fawọn to nilo wọn.”

Ọmọkunrin kan tọjọ ori ẹ ko ju mẹsan-an lọ lo pa gbẹyin ti aṣiri fi tu. Ahmad lorukọ ọmọ ti wọn pa gbẹyin yii, ileekewu lo ti de to fi di pe wọn o ri i mọ.

Nigba ti wọn yoo ri i, oku ẹ ni wọn ba ninu ile akọku kan laduugbo Barakallahu, o tiẹ ti n jẹra paapaa ki wọn too ri i.

Iyawo mẹta ati ọmọ mọkandinlogun (19) ni ọkunrin apaayan yii ni, ṣugbọn ko ṣe wọn ni ṣuta, awọn ọmọ ọlọmọ lo n pajẹ.

Leave a Reply