Mọ mọ ẹni to fẹẹ le mi nipo ọba-Oluwoo

Olajide Kazeem

Bi awọn afọbajẹ ilu Iwo ṣe n bẹ ijọba, ti wọn si n wa gbogbo ọna ti ọba wọn, Oluwoo ti ilu Iwo, Abdul-Rasheed Akanbi, yoo ṣe fi ori apere silẹ, Kabiyesi naa ti sọ pe, oun ti mọ ẹni ti inu oun n bi gidigidi.

Ni kete ti iroyin ọhun gbalu kan ni akọwe iroyin fun ọba alaye naa, Alli Ibrahim, ti gbe atẹjade kan sita, eyi ti Oluwoo fọwọ si. Ohun ti Kabiyesi si sọ ni pe, oun ti mọ ẹni to fẹẹ le oun kuro lori ipo, ati pe awọn afọbajẹ ti wọn n tọwọ bọwe kiri, ti wọn n bẹ ijọba Ọṣun ko yọ oun danu yẹn, o lẹnikan to n lo wọn.

Oluwoo fi kun un pe ọkunrin kan ti awọn jọ du oye mọ ara awọn lọwọ lasiko tawọn eeyan Iwo n wa Oluwoo tuntun ni ko gba kadara, to n lepa oun kiri lori bi oun yoo ṣe fipo ọhun pitan.

Kabiyesi fi kun un pe ariwo ti wọn n pa kiri ko ba oun lẹru, nitori pe gbogbo awọn eeyan Iwo naa lo mọ pe asiko ti oun dori apere awọn baba nla oun yii, ilọsiwaju nla lo ti ba ilu naa. Bakan naa lo sọ pe ẹni to n lo awọn oloye ọhun ko ṣẹṣẹ maa gbiyanju lati ti oun lulẹ, ṣugbọn ti gbogbo akitiyan ẹ n ja sasan.

Laipẹ yii lawọn oloye bii mejila kọ lẹta si gomina ipinlẹ Ọṣun pe ki gomina rọ Oluwoo loye, nitori itiju nla to n ko ba ilu naa, ati pe ẹlẹwọn eeyan kan bayii ni tẹlẹ lorilẹ-ede Amẹrika lọhun-un, ati ni Canada.

 

Leave a Reply