Ọlawale Ajao, Ibadan
Iyawo ile kan, Modupẹ Oyelade, ti rọ kootu ibilẹ Ọja’ba to wa laduugbo Mapo n’Ibadan lati fopin si igbeyawo ọlọdun mẹtadinlogun (17) to wa laarin oun atọkọ ẹ, Aderẹmi Oyelade, o lọkunrin naa fẹẹ foun ṣoogun owo.
Modupẹ, ẹni to fi adugbo Iyana-Church n’Ibadan ṣebugbe sọ lỌjọruu, Wẹsidee, to kọja pe ife ẹtan lọkọ oun ni si oun ati pe ọpọlọpọ irọ lo pa foun lati fi tan oun jẹ ti oun fi gba lati fẹ ẹ nigba naa lọhun-un.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “mo fẹẹ kawe giga, ko jẹ ki n ka a. Bẹẹ, mi o beere owo lọwọ ẹ, emi ni mo fẹẹ ran ara mi. Awọn ọmọ wa gan-an tun n sọ fun un pe ti mo ba kawe ọhun, ṣebi fun anfaani gbogbo wa naa lo maa jẹ.
“Aṣe nitori pe oun ọkọ mi ko kawe ni ko ṣe fẹ ki emi naa kawe. Ẹni to ti kawe jade ni yunifasiti lo pera ẹ fun mi ki n too fẹ ẹ, bẹẹ ko niwee ẹri iwe girama paapaa lọwọ. Mo ti bi gbogbo ọmọ tan fun un ki n too mọ pe ko niwee ẹri iwe girama gan-an lọwọ depodepo ti yunifasiti. Ẹyin igba yẹn lawọn ẹ̣bi mi fun mi lowo ti mo fi lọ si UNIOSUN (Fasiti Ipinlẹ Ọṣun) bo tilẹ jẹ pe mo pada da owo yẹn pada fun wọn.”
Nigba to n fẹsun kan ọkọ ẹ pe o fẹẹ foun ṣoogun owo, Modupẹ ṣalaye pe, “Ọpọ igba ni mo maa n lalaa pe o gbe igba le mi lori. Mo tun maa n ri igbá yẹn loju aye gan-an, nibi igun yara wa. Ṣugbọn ti mo ba bi awọn ọmọ mi leere pe ṣe wọn ko ri igba ninu yara ni, wọn aa lawọn ko ri igba kankan.
“Mo lọọ ri wolii, wọn lọkọ mi fẹẹ fi mi ṣoogun owo ni. Iyẹn lo jẹ ki ẹru ẹ ba mi ti mo fi sa kuro ninu ile ko too di pe awọn pasitọ ba wa pari ẹ ni ṣọọṣi ti mo fi pada sinu ile.
“Igba kan wa to ran awọn háyákilà si mi. Mo jade nile nirọlẹ ọjọ kan lawọn agbanipa n sọ fun mi loju ọna pe maddam, ẹ ki i ṣe ẹni ta a le pa ni o. Ẹ yee rinrin alẹ o, nitori wọn ti sanwo ẹmi yin o. Bi wọn ṣe sọ bẹẹ lemi naa yaa tete fere ge e.”
Pẹlu bi olujẹjọ, Aderẹmi Oyelade, ko ṣe fara mọ ki wọn tu igbeyawo naa ka, o kọ lati fẹsun kan iyawo ẹ niwaju igbimọ awọn adajọ. Ṣugbọn o ni irọ lobinrin naa pa mọ oun, oun ko gbero lati fi i ṣoogun owo.
Amọ ṣaa, igbimọ awọn adajọ kootu naa, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla ti fopin si igbeyawo ọlọdun mẹtadinlogun to seso ọmọ mẹrin naa.
Olupẹjọ ni wọn yonda awọn ọmọ mẹrẹẹrin fun. Wọn si pa baba wọn laṣẹ lati maa san ẹgbẹrun lọna ogun Naira (N20,000) fun iya wọn loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounje.ọn ọmọ wọnyi.