Mo ti dariji Tinubu o- Bode George

Adewale Adeoye

Alagba Bode George, to ti figba kan jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ yii ti sọ pe oun ti dariji aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ yii, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu patapata.

O sọro yii di mimo lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, nile rẹ, niluu Ikoyi, lasiko to n ba awọn oniroyin kan sọrọ.

Nigba to n fesi si ọkan lara ibeere tawọn oniroyin kan beere lọwọ rẹ boya o le ba Tinubu ṣiṣẹ papọ bi aarẹ tuntun naa ba pe e,  ọkunrin yii sọ pe, mi o ba Tinubu ja mọ rara, orileede mi ni Naijiria, ibẹ ni wọn ti bi mi, ibẹ naa ni mo si ti dagba, o yẹ ki n le ṣe fawọn araalu mi bi mo ba ni lọwọ lati ṣe fun wọn, eyi ki i ṣohun toju ko ri ri rara.

O ṣalaye pe oun ti dariji Tinubu patapata bayii, ṣugbọn oun ko le gbagbe gbogbo ohun to ṣe.

Ninu ọrọ rẹ nipa isakoso ijọba Buhari, ọkunrin to maa n pe ara rẹ ni ọmọ Eko pataki yii sọ pe, ‘‘Ki i ṣohun to fara sin rara pe ifasẹyin nla gbaa ni iṣakooso ijọba Aarẹ Buhari mu ba awọn eeyan orileede yii ni gbogbo ọna pata, itan ko si ni i gbagbe ọkunrin naa fun bo ṣe ko wa sinu iyọnu bayii’’.

Siwaju si i, agba oloṣelu yii ni bi wọn ba ni koun gbe iṣakoso ijọba Buhari lori oṣuwọn, ijọba rẹ ko gbe iwọn kankan rara niwaju oun. O kuna patapata lati fopin sọrọ bawọn janduku ṣe n paayan nigba gbogbo lorileede yii, bẹẹ ohun to sọ nigba to n ṣepolongo fawọn araalu ni pe laarin ọdun kan, oun yoo kapa awọn afẹmiṣofo ọhun patapata. ‘‘Bi wọn ba ni ki n gbe aṣeyọri rẹ lori ida ọgọrun-un, ida marun-un pere ni ma a fun un, ida marun-un ọhun paapaa, ma a tun yẹ ẹ wo daadaa ni.

‘‘Ki i ṣohun to daa rara bi Aarẹ Buhari ṣe  kuna nipa ojuṣe akọkọ rẹ, ko pese eto aabo to kunju oṣuwọn fawọn araalu orileede yii rara, ẹmi awọn araalu ko de nigba iṣakooso Aarẹ Buhari, ojoojumọ lawọn ajinigbe fi n ji awọn araalu gbe bo ti ṣe wu wọn, ohun kan to daju daadaa nibẹ ni pe, itan ko ni i gbagbe Aarẹ Buhari rara lori bo ti ṣe doju gbogbo nnkan ru fawọn ọmọ orileede yii, akooba nla gba a ni ijọba Aarẹ Buhari jẹ fawọn ọmọ orileede yii’’.

Bẹẹ o ba gbagbe, aipẹ yii naa ni Alagba Bode George ṣe atupalẹ nipa iṣakooso ijọna Aarẹ Muhammadu Buhari to si sọ pe, ohun kan to daju ṣaka ni pe, itan bi Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari ṣe fiya nla jẹ gbogbo awọn ọmọ orileede yii, ko ni i pare laelae nitori pe, fun odidi ọdun mẹjọ gbako ti Aarẹ Buhari fi wa nipo olori orileede yii, lo fi fiya jẹ awọn araalu, to si tun kuna patapata lati mu gbogbo awọn ileri to ṣe lakooko to n ṣepolongo ibo lọdun 2015 ṣe fun wọn.

Leave a Reply