Mo ti mọ pe wahala ni Buhari yoo ko ba ọmọ Naijiria-Fayoṣe

Aderohunmu Kazeem

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Peter Ayọdele Fayoṣe, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ṣoja ṣe pa awọn ọmọ Naijira nipakupa.

Lori ẹrọ abẹyẹfo ẹ, (Twitter) lo ti sọ pe ohun ibanujẹ lo jẹ bi awọn ṣoja ṣe pa awọn ọdọ Naijiria, bẹẹ lo fi kun un pe oun pariwo nigba naa lọhun-un pe Buhari ko ni ohun rere kankan lọkan to fẹẹ ṣe ju ki wọn ṣaa ti pe e ni Aarẹ Naijiria lẹẹkan si i.

O ni, “Mo wi nigba yẹn pe ko si bi a ṣe fẹẹ wọsọ funfun balau fun ẹlẹdẹ ti ko ni i ba a jẹ. Buhari ko ni aanu ẹnikẹni loju, bẹẹ ni ko yẹ nipo iṣelu rara. Ọkunrin yii ko ni ohun rere fun ọmọ Naijiria ju agbako to ko ba wọn yii lọ.”

Leave a Reply