Mo ti sọ tẹlẹ pe iru akọlu ti wọn ṣe si reluwee ilẹ wa yii maa waye-Amaechi

Jọkẹ Amọri
Minisita fọrọ igboke-gbodo ọkọ nilẹ wa to tun ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Rivers, Rotimi Amaechi, ti sọ pe oun ti sọ tẹlẹ pe o ṣee ṣe ki awọn janduku maa da awọn ọkọ reluwee ti awọn n gbe soju ọna yii lọna pẹlu bi ko ṣe si ipese awọn ohun eelo aabo to yẹ si awọn reluwee naa ati oju ọna.
Lasiko ti minisita yii lọọ ṣabẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lo ṣalaye pe to ba jẹ pe awọn ohun eelo igbalode ati awọn kamẹra to yẹ ba wa lati maa kiyesi awọn reluwee naa bi wọn ti n rin, atawọn kamẹra igbalode mi-in jẹ lilo lati fi mojuto ohun gbogbo bo ṣe n lọ, iru iku buruku to pa awọn eeyan naa ko ni i waye rara.
O ni o maa n jẹ ohun to buru nigba ti awọn ba beere fun owo lati ra iru awọn nnkan bayii, ti awọn kan ti wọn ro pe awọn lagbara yoo si maa lo agbara wọn lati di iru nnkan bẹẹ lọwọ tabi ti wọn ko ni i ya si i.
‘‘A mọ ohun to le ṣẹlẹ, a si mọ pe o yẹ ka ni ẹrọ igbalode to wa fun eto aabo. Ti a ba ni iru nnkan bẹẹ, ko sẹni ti yoo le duro loju ọna ti awọn ọkọ naa n ba. Mo sọ fun wọn pe ẹmi yoo ṣofo pẹlu bi a ko ṣe gbe igbesẹ yii, ẹmi si ti ṣofo bayii, eeyan mẹjọ lo ku, awọn bii mẹẹẹdọgbọn si wa ni ileewosan ti wọn n gba itọju.
‘A o ti i mọ iye eeyan ti wọn ji gbe. Biliọnu mẹta ni owo to yẹ ka fi ra awọn nnkan aabo yii, ṣugbọn ohun ti a ti sọnu bayii ti ju biliọnu mẹta lọ. A ti padanu awọn ọna reluwee, a padanu reluwee, bẹẹ la si padanu awọn to n wa a.
A ti padanu awọn eeyan abẹmi lori biliọnu mẹta ti wọn n ta ohun eelo to yẹ ka ra lati fi dena eleyii.
‘‘Aimọye awọn iwe to le mu anfaani ati ilọsiwaju ba orileede wa to jẹ pe wọn kan ko wọn jọ lai fọwọ si i nitori pe awọn kan ti wọn gbagbọ pe awọn lagbara fẹẹ ṣe afihan agbara wọn.’’
Amaechi ni nigba ti oun beere fun biliọnu mẹta lati fi ra awọn ohun eelo naa, bii irinwo Naira (400) ni wọn n ṣẹ owo ilẹ wa si ti ilẹ okeere, ṣugbọn ni bayii, o ti di ẹẹdẹgbẹta Naira. ‘Nigba teeyan ba fi ọkan tootọ lọ lati beere nnkan, ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan si n di i lọwọ, iru nnkan bẹẹ maa n biiyan ninu gidigidi.’
O fi kun un pe ko yẹ ki ẹnikẹni di ẹbi ọrọ naa le Aarẹ Buhari lori rara, nitori awọn kan ti wọn lagbara ti sọ ara wọn di okuta idena si ilọsiwaju orileede yii.
Ni bayii, a gbọ pe Aarẹ Buhari ti buwọ lu owo to yẹ ki wọn fi ra awọn ohun eelo ti wọn yoo fi daabo bo oju ọna, ọkọ oju irin naa ati awọn ero to n wọ ọ.

Leave a Reply