Mo ti tọrọ aforiji lọwọ Ọlọrun lorukọ awọn ọba to n bọ oriṣa- Oluwoo

Oluwoo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi,  ti sọ pe mimu oriṣa sinsin wọnu aafin jẹ ajeji si ipo ọba.

Oluwoo, ninu atẹjade kan to fi sita, ṣalaye pe Ọlọrun ni ipilẹ gbogbo ade ti awọn ọba n de, o si jẹ ohun irira lati maa fi oriṣa pe Ọlọrun nija.

Kabiesi sọ siwaju pe aṣoju Olodumare ni awọn ọba ninu aye, iwa ati iṣe wọn si gbọdọ jẹ mimọ, lai faaye pe alagata laarin awọn ati Ọlọrun.

O ni ohun ajeji ni ki ọba maa bọriṣa nitori ade jẹ ohun ọwọ, aṣẹ ati ini Ọlọrun. O ni arifin nla ni niwaju Ọlọrun.

Oluwoo parọwa si awọn ori-ade lati bọwọ to tọ fun Olodumare, ẹni ti wọn n ṣoju lori itẹ, ki wọn si faaye gba aṣẹ rẹ nikan lati bori.

“Ọlọrun ni Ọba, o tumọ si pe ile Ọlọrun ni aafin, nibi ti awọn ọba n gbe. Ohun kan ṣoṣo to jẹ orogun fun Ọlọrun ni oriṣa nitori pe ọba ki i pe meji laafin.

“Ko gbọdọ si oriṣa ninu aafin. Ẹ lọọ sọ fun awọn ori-ade. O fẹyawo, iyawo yẹn waa gbe ọkunrin miiran wa sinu ile, bawo lo ṣe fẹẹ ri lara yin. Ohun ti awọn ọba ilẹ Yoruba n ṣe fun Ọlọrun niyẹn, sibẹ, wọn n reti pe ki Ọlọrun bukun awọn.

“Ẹnikẹni ninu awọn baba nla wa ti wọn jẹ ori-ade ti wọn ba n sin oriṣa ko ṣe nnkan to dara. Mo ti gbe igbesẹ akin lati ba wọn tọrọ aforijin. Ewu nla ti ohun ti wọn ṣe yi mu ba wa pọ pupọ.

“Ma a ṣaaju ọna lati tun gbogbo awọn nnkan ti ko tọna yii ṣe. A le gboriyin fun awọn baba nla wa ti wọn ba ṣe daradara, ṣugbọn a ko gbọdọ maa sin wọn, ti awa naa ko ba fẹẹ di oriṣa akunlẹbọ fun awọn ọmọ wa.

“Ọlọrun nikan ni Ọba. Oduduwa ba awọn oriṣa ja, o si ṣẹgun Ọbatala. Orukọ Olodumare to ga ju lọ ni ‘Ọba’. Ko si ẹlomiran to n jẹ orukọ yẹn yatọ si awọn ori-ade. Aṣoju Olodumare ni wa. A gbọdọ bọwọ fun un, ki a si jawọ ninu ohunkohun ti ko fara mọ. Mo pe gbogbo awọn ọjọgbọn aye nija lati sọ fun mi, oriṣa ti Oduduwa fori balẹ fun.

“Aṣa ati iṣe Yoruba lo dara ju lọ lagbaaye. Ohun kan ṣoṣo ti awọn ọba le ṣe lati mu ipo wọn gbayi ni lati jawọ ninu oriṣa sisin”

Leave a Reply