Mọgaji agboole fa irun abẹ tẹgbọn-taburo n’Ibadan, o loun fẹẹ fi tun ọjọọwaju wọn ṣe ní

Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori to fa irun abẹ awọn tẹgbọn-taburo lẹyin to tọwọ bọ wọn labẹ tan, baba ẹni ọgọta ọdun kan,  Mọ́gàjí Najeem Oríaré ti dero atimọle ajọ NSCDC, iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps, ta a mọ si sifu difẹnsi, ẹka ipinlẹ Ọyọ.
Oloye Najeem, to jẹ Mọgaji agboole Aríọrí, nigboro Ibadan, lo pe awọn ọmọ ìyá, ọmọ baba kan naa meji yii, Rọkiba Akanji ati Abibat Akanji,  wọ inú ile ẹ to wa laduugbo Fanawọle, lagbegbe Apẹtẹ, n’Ibadan, lasiko ti wọn n bọ lati ibi ti iya iya wọn tó n tọju wọn ran wọn.
ALAROYE gbọ pe lẹyin ti baba ti wọn n pe ni Aarẹ Aworawọ yii fi ọrọ didun fa awọn ọmọge naa (ọmọọdun mẹtala ati ọmọọdun mẹ́tàdínlógún,) loju mọra tan lo pe wọn wọ inu yara ẹ lọkọọkan, to si huwa ti ko bojumu ọhun fún wọn.
Lẹyin naa lo fun awọn
 ọmọbirin ta a forukọ bo laṣiiri wọnyi lẹgbẹrun kan naira (N1,0000) pẹlu ìkìlọ pe wọn kò gbọdọ royin gbogbo nnkan ti oun ṣe fun wọn yii fun ẹnikẹni, ati pe lọjọkọjọ ti wọn ba sọrọ àṣírí náà fun ẹda Ọlọrun kan niku yoo pa wọn.
Gẹgẹ bíi alaye ti Rokiba ati Abiba tá a fi ojúlówó orukọ wọn bo wọn laṣiiri ṣe, wọn ni gbogbo igba ti Mọgaji Ariọri n gba irun abẹ awọn, to n tọwọ bọ awọn loju ara, niṣe lo dà bíi ẹni pé awọn ko mọ ohun tó n ṣẹlẹ, afi nigba ti awọn dele. Eyi lo sí mú kí àwọn royin ohun ti baba agba naa foju awọn ri fun iyaagba to n tọju awọn, pẹlu awon agba aduugbo naa kan.
Ṣugbọn Aarẹ Aworawọ sọ pe òun ko gbèrò lati ṣe awọn ọmọdebinrin náà nijanba bi ko ṣe lati ran wọn lọwọ nipa bi ọjọ iwaju wọn yóò ṣe dáa.
Ṣugbọn awijare rẹ ko tẹ awọn obi Rokiba ati Abiba lọrun, wọn ni niṣe lo fẹẹ lo awọn ọmọ awọn fún ètùtù ọla, afi ki ijọba ati gbogbo ọmọ Naijiria gba awọn lọwọ baba oloogun to n pe ara ẹ laafaa náà.
Awọn ọdọ àdúgbò ko tilẹ mu ọrọ naa ni kekere ní tiwọn, wọn ti bẹrẹ si i da sẹria fún baba, wọn ni ko jẹwọ ohun to fẹẹ fi irun oju ara ọmọọlọmọ ṣe.
Nibi ti wọn sì ti n mura lati dana sun ile ẹ lawọn oṣiṣẹ sifu difẹnsi ti dé lati gba a silẹ.
Atimọle àjọ naa ni baba ẹni ọgọta ọdun ọhun wa titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, Alukoro ajọ NSCDC, Ọgbẹni Oluwọle Oluṣẹgun, bu ẹnu àtẹ lu igbesẹ ti awọn ọdọ adugbo naa gbe nipa bi wọn ṣe fẹẹ mu idajọ afurasi naa latọwọ ara wọn dipo ki wọn fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti

Leave a Reply