Mohammed ṣa ọmọ bibi inu rẹ pa, ladajọ ba ju u sẹwọn ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ti ni ki arakunrin Yahaya Mohammed maa lọọ gbafẹfẹ lọgba ẹwọn fẹsun pe o ṣa ọmọ bibi inu rẹ ti ko ju ọdun mẹwaa lọ, Aliyu Mohammed, lada, to si gbabẹ ku.

Mohammed to jẹ olujẹjọ ni wọn sọ pe o ran ọmọkunrin rẹ niṣẹ, to si ni ko sare jiṣẹ naa, eyi ti baba rẹ ka si iwa igberaga, lo ba binu lẹ ada mọ ọ, ada naa ba ọmọ rẹ ni koko ẹṣẹ, ni ẹjẹ ba n tu jade bii agbara, wọn sare gbe e lọ sileewosan, sugbọn nibi ti wọn ti n tọju ẹ lo ti dagbere faye.

Olupẹjọ, Moshood Agboola, waa rọ Ile-ẹjọ lati fi ọkunrin ọdaran naa si ahamọ tori pe ẹsẹ rẹ lagbara kọja eyi ti wọn le gba beeli rẹ.

Magistreeti Saliu ti waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Mohammed si ọgba ẹwọn, to si sun igbẹjọ si ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

 

Leave a Reply