Mọlẹbi aṣọbode tawọn Boko Haram ji gbe bẹbẹ fun iranlọwọ ijọba

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn mọlẹbi DSC Jimoh Folowoṣẹle tawọn ajinigbe ti wọn fura si bii Boko Haram gbe nipinlẹ Yobe ti rawọ ẹbẹ sileeṣẹ aṣọbode ilẹ yii pe ki wọn ma jẹ ki ọkunrin naa ku sinu igbekun.

Folowoṣele, ọmọ Aramọkọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, la gbọ pe awọn Boko Haram mu oun tawọn meji mi-in ni Geidam, nipinlẹ Yobe, lọjọ kẹsan-an, oṣu yii, lasiko ti wọn wa lẹnu iṣẹ.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, aburo ọkunrin naa, Idowu Folowoṣele, sọ ọ di mimọ pe inu ibẹru nla ni mọlẹbi naa wa bayii nitori lati ọsẹ meji sẹyin ni wọn ti ji i gbe.

Idowu ni lẹyin ti ileeṣẹ aṣọbode ti sọ pe ootọ niṣẹlẹ naa, awọn ko gbọ nnkan kan lori igbesẹ ti wọn n gbe ati igbiyanju wọn.

O waa bẹ ọga-agba ileeṣẹ naa, Ajagun-fẹyinti Hameed Ali, lati sa gbogbo ipa lori bi Folowoṣẹle yoo ṣe bọ ninu igbekun. O ni awọn mọ ọga agba naa bii ẹni to jafafa, to si loootọ, idi niyi tawọn fi n kegbajare iranlọwọ si i.

Bakan naa ni ọrẹ Folowoṣele kan, Ọgbẹni Fọla Ayedun, sọ pe bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ aṣọbode ti n gbe awọn igbesẹ kan, o yẹ ki wọn jẹ ki mọlẹbi mọ bo ṣe n lọ, paapaa iyawo atawọn ọmọ.

O ni loootọ ni ọrọ ijinigbe gba ọgbọn, awọn ko si ni ki ileeṣẹ naa maa kede igbesẹ ti wọn n gbe, ṣugbọn ọrọ ifọkanbalẹ ni mọlẹbi aṣobode naa nilo lasiko yii nitori lati bii ọjọ mẹwaa sẹyin ni wọn ti n ṣaisun.

Leave a Reply