Adewale Adeoye
Bi a ba ri ẹnikan to sọ pe ọrọ iku gbajumọ akọrin nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, maa too dopin, onitọhun n parọ ni o, nitori pe awọn ẹbi oloogbe naa ti fariga bayii, wọn ni awọn ko fara mọ abajade esi ayẹwo tijọba ipinlẹ Eko gbe sita nipa iku to pa ọmọkunrin olorin naa pe aṣilo egboogi oloro lo ṣokunfa iku rẹ. Wọn ni afi ki wọn lọọ ṣe omiran tijọba Eko ko ni i lọwọ si rara.
Awọn ogbontarigi ninu iṣẹ iṣegun oyinbo lati ileewosan ijọba ipinlẹ Eko, ‘Lagos State University Teaching Hospitals’ (LASUTH), eyi ti Ọjọgbọn Sunday Ṣoyẹmi ṣaaju ikọ ọhun ni wọn ṣayẹwo si oku oloogbe naa, ti wọn si sọ pe aṣilo egboogi oloro lo ṣokunfa iku rẹ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni ẹbi oloogbe naa pe ipade awọn oniroyin kan, nibi ti lọọya ẹbi naa, Ọgbẹni Wahab Shittu, ti gba ẹnu gbogbo ẹbi sọrọ pe eru wa ninu abajade esi ayẹwo tijọba Eko ṣe fun oloogbe naa, nitori pe ọtọ ni abajade esi ayẹwo tileeṣẹ ọlọpaa orileede yii gbe jade, to si yatọ gede-gede si eyi tijọba ipinlẹ Eko gbe sita bayii. Mọlẹbi oloogbe ni niwọn igba tawọn abajade esi ayẹwo tijọba ipinlẹ Eko ṣe ati eyi tawọn miiran ṣe ti ta ko ara wọn bayii, o ṣe pataki fawọn lati tun ṣe omi-in, leyii tijọba ipinlẹ Eko ko ni i lọwọ si, lati le mọ koko ohun to pa Mohbad.
Wọn bẹnu atẹ lu bawọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ iku oloogbe naa, paapaa ju lọ, bi aṣiri irọ banta-banta ti wọn pa pe awọn n reti abajade esi ayẹwo kan tawọn lọọ ṣe fun oloogbe naa l’Oke-Okun, to si jẹ pe wọn ko debẹ rara ṣe tu. Wọn waa rawọ ẹbẹ si ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, I.G Kayọde Ẹgbẹtokun, pe ko da sọrọ iku oloogbe naa, ki iya naa ma jẹ awọn gbe.
Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Awa ẹbi Oloogbe Mohbad ko fara mọ abajade esi ayẹwo tijọba ipinlẹ Eko gbe sita lori iku ọmọ wa rara, ejo ọrọ naa lọwọ ninu, awọn ibi kọọkan si wa ninu abajade esi ayẹwo ọhun to ṣidii ijọba silẹ, o fi han gbangba pe eru wa ninu rẹ. Ẹbi Alọba atawọn ololufẹ oloogbe naa lagbaaye lawọn fẹẹ mọ ibi gan-an ti wọn ti ṣe ayẹwo sokuu oloogbe naa, ki wọn le mo bo ṣe jẹ ojulowo si. Awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to wa ninu ibi ti wọn sọ pe wọn ti ṣe ayẹwo naa, a ko si fara mọ bijọba ipinlẹ Eko atawọn ọlọpaa orileede yii ṣe ṣe ọrọ iwadii iku oloogbe naa rara. Paapaa ju lọ, nigba ti wọn tun sọ awawi kan nipa iwadii naa pe awọn ko le fidi ohun to pa a mulẹ daadaa, niwọn igba to jẹ pe oku rẹ ti n jẹra ko too di pe wọn hu u jade lẹyin ti wọn sin in. Fun idi eyi, a ko gba abajade esi ayẹwo tijọba ipinlẹ Eko ṣe sokuu oloogbe naa wọle rara, afi ki wọn tun omi-in ṣe lọdọ awọn ogbontarigi onimọ ijinlẹ nipa ayẹwo oku, ki wọn si ma fi esi naa jafara rara bo ba ti jade.