Mọsalasi ati ṣọọṣi ni wọn ti n dawo jọ bayii lati doola awọn mẹreerin ti wọn ji gbe lọna Omu-Aran

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji awọn arinrin-ajo mẹrin: Sunday Balogun, iyawo rẹ, Iya Mary, Taye, ọmọọṣẹ Sunday, ati Kẹhinde rẹ, gbe ni loju ọna Oke-Onigbin si Omu-Aran lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ti n beere fun miliọnu mẹwaa owo itusilẹ bayii.

Ẹni kan to sun mọ mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe,  Arabinrin Laoye Seyifunmi, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ibi igbeyawo ni awọn arinrin-ajo ọhun lọ lati ilu Oke-Onigbin si Obo Ayegunlẹ, sugbọn wọn ko sọwọ awọn ajinigbe, ti wọn si ji wọn gbe lọ. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni awọn araalu Oke-Onigbin to ri mọto Sunday lẹba ọna ni wọn fi mọ pe wọn ti ji wọn gbe.

Ko pẹ ni awọn to ji wọn gbe pe mọlẹbi, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ. Wọn dunaa-dura, awọn mọlẹbi gbe miliọnu kan naira lọ, ṣugbọn wọn kọ ọ, wọn ni ki i ṣe owo awọn, miliọnu mẹrin ni wọn pada taku si pe wọn yoo gba jalẹ.

Gbogbo ileejọsin, mọsalasi ati ṣọọṣi ni wọn ti n dawo jọ bayii lati doola awọn mẹreerin to wa lakata awọn ajinigbe ọhun.

Leave a Reply