Moshood ti wọn ka ẹya ara-oku mọ lọwọ niluu Gbọngan ti wa lakolo ọlọpaa

Florence Babaṣọla

 

Ọwọ agbarijọpọ awọn ẹsọ alaabo nipinlẹ Ọṣun, iyẹn Joint Tax Force, ti tẹ ọkunrin kan, Moshood Anifanikun, ti wọn ka ẹya ara oku mọ lọwọ niluu Gbọngan, nijọba ibilẹ Ayedaade, nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn alajọgbele Moshood ni Iyana Gbayanrin, nitosi ọja Ayepe, ṣakiyesi pe o gbe nnkan kan wọle ninu apo.

Bo ṣe wọle ni wọn ni oorun abami ọhun gba gbogbo inu ile kan. Iyawo Moshood to n ta raisi sise lawọn eeyan kọkọ lọọ ba, wọn ni ko lọ tẹ ọkọ rẹ ninu lati mọ nnkan to wa ninu apo to gbe wọle.

Nigba ti ọkunrin yii ri i pe aṣiri fẹẹ tu, o gbe apo naa, o si lọọ gbe e pamọ sinu agbo ọgẹdẹ to wa lẹyinkule ile ti wọn n gbe.

Awọn araale lọọ fi ọrọ naa to awọn ẹṣọ alaabo JTF ti wọn wa lorita Gbọngan leti, awọn yẹn si wa pẹlu mọto meji, wọn gbe Moshood lọ si agọ wọn.

Bi wọn ṣe lọ tan lawọn araadugbo tun bẹrẹ si i wa ibi to gbe apo yẹn pamọ si, ko si pẹ rara ti wọn fi ri i ninu agbo ọgẹdẹ. Wọn tun pada lọọ sọ fun awọn ọlọpaa, wọn si gbe Moshood pada wa sibẹ lati fi ọwọ ara rẹ gbe nnkan to wa ninu apo naa jade.

Lẹyin eyi ni wọn da Moshood, ti wọn pe ni ọmọ Ile-Ẹju, niluu Ọde-Omu, pada sakolo wọn.

Gbogbo igbiyanju wa lati ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lori iṣẹlẹ naa ko so eso rere nitori ko gbe foonu rẹ ni gbogbo igba ti a pe e.

Leave a Reply