Mọto bọginni mẹtala ni EFCC ba lọwọ awọn ọmọ Yahoo nibi ti wọn ti n nawo bii ẹlẹda

Faith Adebọla

Yoruba bọ, wọn ni ‘ounjẹ olounjẹ ki i jẹ ka jẹ oun jẹẹjẹ’, nibi tawọn gende mọkanlelọgbọn yii ti n jaye alabata, ti wọn n nawo bii ẹlẹda nibi ariya kan ti wọn ko ara wọn jọ si lotẹẹli kan niluu Benin, nipinlẹ Edo, ibẹ lọwọ ajọ EFCC ti ba wọn lọjọ Aje, Mọnde yii, ọkọ ayọkẹlẹ bọginni mẹtala ni wọn gba nidii wọn.

Awọn afurasi ọdaran ọhun, ti wọn ni jibiti ori atẹ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo Yahoo’ ati ‘Yahoo plus’ ni wọn n ṣe, ti wa lara awọn ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nni, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), n wa kiri tipẹ.

A gbọ pe ni nnkan bii oṣu meji sẹyin lawọn kan lara awọn apamọlẹkun-jaye ẹda yii lọọ dana ariya kan si otẹẹli to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta kan niluu Benin, ti fidio kan si ṣafihan wọn nibi ti wọn ti n ṣe yala-yolo, wọn gori ọkọ ayọkẹlẹ wọn, wọn bẹrẹ si i fọn beba owo naira fawọn ero to n woran wọn, bẹẹ ni wọn n tu ọti bia ati ọti lile danu, wọn lawọn n sọdun owo ti wọn pa.

Iru ariya gbigbona yii ni wọn lawọn ọmọ ‘yahoo’ yii tun fẹẹ ṣe, ti kaluku wọn fi gbe awọn ọkọ ti wọn fowo olowo ra wa, ti wọn si kun gbogbo agbala otẹẹli naa, laimọ pe olobo kan ti ta awọn ẹṣọ EFCC to ti n dọdẹ wọn bọ, bi wọn ṣe fẹẹ dana ariya naa lọwọ ba wọn, wọn si ko gbogbo wọn.

Orukọ awọn tọwọ ba naa ni Essien Sunday, Joseph Nwosu, Samuel Victor, Abdurahman Abudulahi, Uwaifo Destiny, Osaro Osarere, Favour Oleye, Smart Okunvobo, Oduwa Osahon, Osaretin Blessed, Frank Osas, Aisosa Kelly, Richard Ehigie, Destiny Omoru, Jacob Kelvin, Aker Kelly, Promise Godspower, Lucky Dickson ati Osamode Efosa.

Awọn to ku ni Osamuyi Aigbe-Egharevba, Ohumumwen Osaremen, Christopher Momodu, Aigbe Destiny, Eti-osa Osamwonyi, Patrick Benson Osaguna, Victor Kenyei, Marvellous Atiti, Gift Ebuehi, Osayi Casmir, Osahenkhoe Godstime ati Paul Okoh.

Ọkọ ayọkẹlẹ mẹtala, ọpọlọpọ kọmputa agbeletan, foonu alagbeeka olowo nla, oogun abẹnugọngọ, ayederu iwe irinna ofururu, ṣeeni, kaadi ipọwo ATM ati owo rẹpẹtẹ ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

Ṣa, gbogbo wọn ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ pẹlu ẹsibiiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ, kaluku wọn ti n ṣalaye ẹnu ẹ, iwadii si ti n tẹsiwaju, ba a ṣe gbọ.

Leave a Reply