Mọto BRT to ni ẹrọ igbalode ninu balẹ sipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni ibamu pẹlu ileri ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ṣe lati ko awọn ọkọ BRT wọ ipinlẹ yii ninu oṣu karun-un, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ, awọn ọkọ bọginni to ni ẹrọ igbalode ninu naa ti balẹ gudẹ bayii. Ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kọkanla, ọsu karun-un, ni wọn ṣi wọn de.

Kọmiṣanna eto irinna nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Gbenga Dairo, to gba awọn bọọsi naa, ṣalaye pe awọn ọkọ yii yatọ si bọọsi atijọ, nitori awọn nnkan eelo to wulo fawọn eeyan to ba wọ ọ wa ninu ẹ.

Kọmiṣanna sọ pe, yatọ si pe awọn ọkọ yii yoo mu inira tawọn eeyan n koju lati ri ọkọ wọ kuro, o tun jẹ ọna iṣẹ fawọn ti yoo maa wa a.  Eyi si jẹ ọkan ninu awọn afojusun Gomina Dapọ Abiọdun, ẹni to fẹ idẹrun fawọn eeyan rẹ, to si n mu ileri rẹ ṣẹ.

‘’ Ọsẹ keji ree ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣeleri pe awọn ọkọ BRT yii yoo de sipinlẹ Ogun, o si mu ileri naa ṣẹ. Iṣi akọkọ (First batch) lawọn eyi. Ọkọ wiwọ to dinwo, to rọrun lati wọ, to si fọkan balẹ leyi, bẹẹ lo si yara ṣaṣa’’  Bẹẹ ni Ọgbẹni Gbenga Dairo wi.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ sọ ọ di mimọ pe awọn ọkọ yii yoo maa na Eko lati Mowe, Sango-Ọta atawọn ibo mi-in nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply