Mọto gbokiti ni marosẹ Eko s’Ibadan, ni ina ba jo awọn ero ọkọ pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ iye eeyan to jona ku ninu mọto kan to gbokiti, to si gbina, ni marosẹ Eko s’Ibadan, iyẹn lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹfa, oṣu karun-un yii.

Alaye ti Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, ṣe lori iṣẹlẹ yii ni pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ kọja ogun iṣẹju ni ijamba naa ṣẹlẹ lori afara marosẹ Eko s’Ibadan.

O ni mọto Rav 4 kan ti nọmba ẹ jẹ LND 13 GS, mọto ayọkẹle Toyota Camry, GGE 369 GJ ati mọto Mazda kan ti wọn ko le da nọmba ẹ mọ ni asidẹnti naa kan.

Akinbiyi sọ pe bọọsi akero ni mọto Mazda naa, oun lo fẹẹ ya awọn yooku silẹ to fi lọọ kọ lu Toyota to yọnu ti wọn paaki silẹ jẹẹjẹ, o si tun kọ lu ọkọ ayọkẹlẹ Camry naa pẹlu.

Nibi to ti n kọ lu wọn kiri naa lo ti ko si wahala, to bẹrẹ si i gbokiti, nibi to ti n gbokiti ni ina ti sọ lara ẹ ti awọn to wa ninu ẹ si jona ku.

‘‘A o ti i le sọ boya ẹkunrẹrẹ ero ni bọọsi Mazda naa ko nigba ti wahala ṣẹlẹ, ṣugbọn ajoku awọn eeyan to jona kọja idanimọ wa nilẹ nibi ti mọto naa gbina si’ Bẹẹ ni Akinbiyi wi.

O fi kun un pe awọn eeyan meji kan naa fara kona, ṣugbọn wọn ko ku. O ni ẹka ti wọn ti n tọju awọn to ba jona lawọn sare ko wọn lọ lọsibitu Jẹnẹra Gbagada.

Nigba to n gba awọn awakọ nimọran pe ki wọn yee fi tiwọn ko ba ara yooku loju popo, Alukoro TRACE tun ba awọn eeyan ti ijamba yii pa eeyan wọn kẹdun, o ni Ọlọrun yoo tu wọn ninu.

 

Leave a Reply