Mọto ijọba ni wọn fi n ko awọn tọọgi kaakiri o

Aṣiri ti tu bayii pe ọpọ awọn tọọgi ti wọn n lọọ da iwọde ti awọn ọdọ n ṣe ru, ti wọn si n hu awọn iwa ibajẹ mi-in kaakiri igboro, awọn eeyan ijọba ni wọn wa lẹyin wọn, awọn ni wọn si n fi mọto wọn gbe wọn kaakiri ibi ti wọn ba ti fẹ ki wọn da wahala silẹ.

Niluu Abujja lanaa, Ọjọ Iṣẹgun, awọn kan ri fidio mọto jiipu to jẹ ti ijọba, ti wọn maa n gbe kiri, ti wọn yoo si da aṣọ dudu bo nọmba wọn, nibi ti mọto naa ti n ja awọn tọọgi silẹ, ti awọn mi-in si tun n sare pada sinu mọto naa lẹyin ti wọn ba ti ṣe iṣẹ aburu wọn tan.

Prado ni mọto naa, ọna Ademọla Adetolunbọ, ni Wuse 2, ni Abuja nibẹ ni wọn ti ya fidio mọto naa nigba to n sọ awọn tọọgi kalẹ, ti awọn tọọgi naa si n sare le awọn ti wọn n le awọn ọdọ to n ṣe EndSARS kiri jẹjẹ tiwọn. Lẹyin ti wọn si kọ lu wọn tan, awọn mi-in sare ninu wọn lati wa pada wọ mọto jiipu naa, ati ikeji ẹ to tun pada waa ko wọn. Bẹẹ ni bọọsi meji wa ni kọrọ lọọọkan, ti awọn tọọgi kun inu rẹ fọfọ, awọn tọọgi yii lo si n fa gbogbo wahala kiri.

O pẹ ti awon eeyan ti n sọ pe awọn ti wọn n ba dukia jẹ, awọn ti wọn n jale, ati awọn ti wọn n paayan ki i ṣe awọn ọdọ ti wọn n fi ehonu han lori ọro SARS, awọn tọọgi ti ijọba ko jade lati waa da eto naa ru ni. Ohun ti wọn ṣe n ṣe eyi ni pe bi awọn tọọgi naa ba n ba nkan jẹ, ti wọn si n paayan, ijọba yoo ni awọn ọdọ yii ni, wọn yoo si le ko awọn ṣọja jade lati le le wọn, tabi yinbọn fun wọn. Bẹẹ lọrọ naa si pada ja si, nigba ti awọn ṣọja yinbọn pa awọn ọdọ ni Lẹki.

Leave a Reply