Mọto kọsitọma ti wọn ni ki Idris fọ lo gbe sa lọ l’Ekoo, ipinlẹ Ogun lọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko ti i pe oṣu kan ti Idris Ayọtunde bẹrẹ si i ba wọn fọ mọto nileeṣẹ kan ni Ṣaṣa, Akowọnjọ, niluu Eko, to fi gbe mọto onimọto ti wọn ni ko ba wọn fọ sa lọ. Ibi ti yoo ta mọto naa si lo n lọ lọjọ kẹrin, oṣu kejila yii, tọwọ fi tẹ ẹ ni marosẹ Abẹokuta s’Ibadan.

Mọto ayọkẹlẹ Ford ti nọmba ẹ jẹ EPE 707 FM, eyi ti i ṣe ti Abilekọ Shofidiya Tosin, ni Idris gbe sa lọ gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyẹmi, ṣe wi.

Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa lẹyin ti wọn mu un labule Alakija, nitosi Olodo, ni nnkan bii  aago mẹjọ alẹ kọja iṣẹju mẹtadinlogun, Idris sọ fun wọn pe oun kawe, oun si ni iwe ẹri ipele akọkọ ti wọn n pe ni ND, nileewe gbogboniṣe kan nilẹ Yoruba yii.

O ni ibudokọ Jimọh, ni Ṣaṣa Akowọnjọ, ni ile ifọmọto toun ṣẹṣẹ riṣẹ si naa wa l’Ekoo. O ni boun ṣe n ṣiṣẹ lọ lọjọ naa lobinrin toun ji mọto ẹ naa de lati fọ mọto rẹ pẹlu ẹrọ kan to jẹ ina lo n lo.

Afurasi yii ni ileeṣẹ mọto fifọ toun n ba ṣiṣẹ ko ni ẹrọ naa, iyẹn loun ṣe pinnu lati ba obinrin naa gbe mọto rẹ lọ si ibomi-in ti wọn ti n fọ mọto nitosi, to jẹ wọn ni ẹrọ to le fọ mọto naa bo ṣe fẹ.

O ni nibi toun ti n wa ọkọ naa lọ ni ero kan  ti wa soun lọkan pe koun kuku maa gbe e lọ, koun lọọ ta a danu, koun si fowo rẹ ṣe faaji ara oun.

Erokereo naa lo ni oun tẹle toun fi dari ọkọ yii gba ọna Ibadan, toun ko si pada si ileeṣẹ mọto fifọ naa mọ.

Ṣugbọn nigba to de Abule Alakija, awọn ikọ to n yẹ mọto to n kọja wo da a duro, wọn beere iwe mọto naa lọwọ ẹ, ni ko ba ri i ko silẹ, bi wọn ṣe bẹrẹ si i fọrọ wa a lẹnu wo gidi niyẹn titi to fi foju han gedegbe pe niṣe lo ji mọto naa.

Ni bayii ṣa, awọn ọlọpaa ti ri obinrin to ni mọto yii, o si ti jẹ ko ye wọn pe boun ko ṣeri Idris mọ loun ti fi iṣẹlẹ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Ṣaṣa.

Ni ti Idris, ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹ sẹka to n ri si iwadii ẹsun bii eyi, ibẹ ni wọn yoo ti gbe e lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply