Moto meji fori sọra wọn lọna Ekiti, leeyan meji ba jona ku patapata

Faith Adebọla

Afi k’Ọlọrun ma jẹ ka rin’na lọjọ tebi n pa ọna o, ijamba ina to ṣẹ yọ nigba tawọn bọọsi Toyota Previa meji kan fori sọ ara wọn lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni Iyin-Ekiti, nitosi Ado-Ekiti, ti mu ẹmi eeyan meji lọ, ọpọ ero ọkọ naa lo si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun bayii.

ALAROYE ni niṣe lawọn ọkọ Toyota mejeeji ọhun n ba ere buruku bọ loju ọna to jẹ kọju-si-mi-n-kọju-si-ọ ọhun, ojiji si ni wọn yọ si ara wọn ni kọna kan ti ko fi ṣee ṣe fun wọn lati pẹwọ, ni wọn ba fori sọ ara wọn.

Ọkan ninu awọn ero ọkọ naa to porukọ ara ẹ ni Taiwo, sọ fawọn oniroyin pe bi ọkọ Toyota Previa yii ṣe takiti sinu igbo lẹgbẹẹ keji ni ina bu gbau, ko si ṣee ṣe fawọn eeyan meji to ṣẹ ku sinu ọkọ naa lati raaye jajabọ, ina naa ka wọn mọ, wọn si jona ku patapata.

Taiwo, toun naa fara gbọgbẹ niwọnba ninu iṣẹlẹ naa sọ pe ọpọ ero lo fọn ka sinu igbo bi awọn ọkọ mejeeji ọhun ṣe gbokiti lọtun-un losi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o lawọn agbofinro to sare lọ sibi iṣẹlẹ naa nigba tawọn gbọ nipa ẹ sọ pe eeyan kan lo jona ku, obinrin si lẹnikan ọhun.

O lawọn alaaanu kan to tete de ibi iṣẹlẹ naa gbiyanju lati yọ obinrin naa ninu ina, ṣugbọn ko ṣee ṣe ki ina naa too fẹju kankan mọ wọn.

Wọn ni wọn ti ko awọn to fara pa lọ sọsibitu ijọba to wa l’Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti n fun wọn ni itọju pajawiri.

Abutu rọ awọn onimọto lati maa rọra sare tori emi o laarọ.

Leave a Reply