Mọto ni Jimoh ji gbe ti wọn fi le e lẹnu iṣẹ ọlọpaa, lo ba kuku ya adigunjale loju paali

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde kan, laipẹ yii, lawọn gende ọkunrin meji kan na ibọn si ọkunrin kan to n jẹ Akiọde John nigi imu laduugbo Akobọ, n’Ibadan, ti wọn si ja a lole ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla rẹ ti nọmba rẹ jẹ GWT 377LX.

Ọsẹ meji lẹyin iṣẹlẹ yii lọwọ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale (SARS) tẹ awọn mejeeji, ko too di pe ijọba apapọ fagi le le SARS. Ọlawale Ọlajide ati Salawu Jimoh lorukọ awọn afurasi adigunjale naa.

Nigba to n ṣafihan wọn fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọyọ to wa l’Ẹleyẹle, Ibadan, Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, sọ pe laduugbo Boluwaji, lọna Ibadan si Eko, lawọn agbofinro ti mu wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju lati lu mọto ọhun ta ni gbanjo.

CP Enwonwu fidi ẹ mulẹ pe iṣẹ ọlọpaa leyi to n jẹ Jimoh n ṣe nigba kan, nitori to huwa to lodi sofin iṣẹ agbofinro nileeṣẹ ọlọpaa ṣe le e danu.

Gẹgẹ bi iwadii akọroyin wa ṣe fidi ẹ mulẹ, lati kekere lole jija ti wa ninu ẹjẹ Jimoh, mọto onimọto ni sajẹnti ọlọpaa yii ji gbe lọ̀dun 2015 ti wọn fi pe e lẹjọ fẹsun ole lẹyin ti wọn gba aṣọ ọlọpaa kuro lọrun ẹ.

Awọn ogbologboo adigunjale to ba pade ninu ọgba ẹwọn ni wọn fi imọ kun imọ rẹ nipa ole jija. Eyi lo sọ ọ di akọṣẹmọṣẹ adigunjale to n fibọn gba mọto kaakiri igboro Ibadan lojuu paali.

Ọwọ Jimoh ni wọn ti ba ọkọ jiipu ti awọn agbofinro tori ẹ mu wọn pẹlu ọkọ mẹta mi-in ti wọn ti ji gbe ṣaaju. Ninu awọn mọto naa la ti ri ọkọ ayọkẹlẹ Honda Accord kan ti nọmba ẹ jẹ ABC, Toyota Camry ti nọmba ẹ jẹ GWT 399 LX, pẹlu ọkọ jiipu mi-in ti nọmba tiẹ jẹ RBC 144 TT. Wọn ti ta awọn ọkọ wọnyi ni gbanjo ki awọn ọlọpaa too lọọ gba wọn lọwọ awọn ti wọn ta wọn fun.

Ninu iṣẹlẹ mi-in to fara pẹ iroyin yii lọwọ ọlọpaa SARS tun ti tẹ afurasi adigunjale kan to n jẹ Oluwaṣọla Adewumi, ọkọ jiipu loun naa ji gbe.

Nibi to ti n gbiyanju ati ta ọkọ ọhun ti nọmba ẹ jẹ YAB 812 EB lawọn ọlọpaa ti mu un pẹlu ẹni to fẹẹ ta ọkọ naa fun, Divine Chinedu, nibi ti wọn ti n dunaa-dura lọwọ laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan.

Gbogbo awọn afuradi ọdaran yii ni wọn ti wa lah́aamọ awọn agbofinro bayii. Laipẹ ni wọn yoo foju bale-ẹjọ gẹgẹ bi ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan.

 

Leave a Reply