Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Bi ki i ba ṣe ti abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun to rin sasiko wahala to ṣẹlẹ latari ijamba ọkọ kan niluu Ọṣunjẹla, ko sẹni to le sọ nnkan ti ọrọ naa iba yọri si.
Ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹwaa kan ti wọn forukọ bo laṣiiri la gbọ pe o fẹẹ sọda si odikeji titi laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ṣugbọn ṣe ni mọto Primera kan to n bọ gbe e hanu nidojukọ orita Ọlọja-Ibala, niluu naa.
Loju-ẹsẹ la gbọ pe awakọ mọto ọhun sọkalẹ, to si gbe ọmọ naa digbadigba sinu mọto pẹlu ọkan lara awọn obi rẹ, wọn mori le ọsibitu LAUTECH, niluu Oṣogbo.
Wọn ko ti i rin jinna rara ti ọmọdebinrin naa fi jade laye, eleyii si bi awọn eeyan ilu naa ninu pupọ. Atọmọde atagba ni wọn fọn soju titi, wọn n fẹhonu han kaakiri, wọn dana sun taya, bẹẹ ni wọn ko faaye gba mọto kankan lati kọja sọna Oṣogbo tabi si ọna Ileṣa, eleyii si fa ọpọlọpọ sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ.
Ohun to n bi wọn ninu ni pe ijamba ọkọ ti maa n ṣẹlẹ ju loju-ọna yẹn, wọn ni aimọye ẹmi lo ti ṣofo latari bijọba ṣe kọ lati ba wọn ṣe idanuduro (Bumps) sibẹ.
Lasiko yii ni abẹnugan ile-igbimọ aṣofin, Timothy Owoẹyẹ, n kọja lọ, o sọkalẹ ninu mọto, o si fẹsẹ rin lọ sorita ti awọn ọdọ naa kora jọ si. O ba wọn kẹdun iku ọmọ naa, o si fi da wọn loju pe ohun ti wọn fẹ ti di ṣiṣe nitori funra oun loun yoo gbe igbesẹ lori rẹ.
Lẹyin ọrọ idaniloju yii lawọn eeyan ilu naa ko ina kuro loju titi, ti wọn si wọ lọ sile awọn to padanu ọmọ wọn.