Mọto tẹ ọlọkada pa lọjọ ọdun Ileya l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lagbegbe Agunbẹlewo, niluu Oṣogbo, lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun yii, to jẹ ọjọ ọdun Ileya ti ran ọmọkunrin ọlọkada kan sọrun aremabọ.

Ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan nijamba naa ṣẹlẹ laarin mọto Toyota Camry kan to ni nọmba Lagos KSF 566 HA ati ọkada kan.

Gẹgẹ bi Alukooro ajọ ẹṣọ ojuupopo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣe fi sita, o ni ṣe ni ọlọkada naa ti ọjọ ori rẹ ko ti i le ju ogun ọdun lọ, fẹẹ ya ọlọkada mi-in silẹ, ṣugbọn ti ọkada rẹ sọ ijanu nu loju-ẹsẹ.

Bayii lo fori sọ mọto kan ti Akinyọade Ayọmide to n gbe lagbegbe Halleluyah Estate, wa. Loju-ẹsẹ si ni ọlọkada naa ku, ti ẹni to gbe sẹyin si fara pa pupọ.

Ogungbemi ṣalaye pe awọn mọlẹbi ọlọkada naa ti gbe oku rẹ ati ọkada rẹ to ni nọmba DTN 82 QB lọ sile wọn.

Awọn ọlọpaa ti gbe mọto naa lọ si ọfiisi awọn VIO, ki awọn ọdọ tinu n bi ma baa ba a jẹ.

 

Leave a Reply