Mọto to n lo ina ẹlẹntiriiki ti de Naijiria, Sanwo-Olu lo ṣi i l’Ekoo

 

Atẹwọ ayọ nla lo waye lowurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ṣi mọto ayọkẹlẹ ti yoo maa lo ina ẹlẹntiriiki dipo epo bẹntiroolu, fun igba akọkọ lorileede yii, niluu Eko.

Gbọngan nla ileeṣẹ Stallion Group Automobile to wa lagbegbe Ọjọọ, nipinlẹ naa, layẹyẹ ọhun ti waye. Ileeṣẹ yii ni wọn ni yoo maa to ẹya ara ọkọ ọhun papọ l’Ekoo, ti yoo si maa ta a jade. Hyundai Kona ni oriṣii ọkọ ayọkẹlẹ akọkọ ti wọn ti ṣe bayii, to jẹ pe ina ẹlẹntiriiki lo fi n ṣiṣẹ, dipo epo bẹntiroolu tabi diisu.

Gẹgẹ bi alaye ti Akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Gbenga Akọsilẹ, ṣe lori iṣẹlẹ amoriya yii, o ni bi wọn ṣe ṣe ọkọ naa ni pe aaye kan wa niwaju mọto yii teeyan yoo ti ṣaja bọ, bii igba teeyan n ṣaaji foonu ninu ina. Ti mọto naa ba ti gba agbara ina ẹlẹntiriiki de iwọn to yẹ, eeyan le maa wa mọto naa kiri lai ra epo si i rara.

Wọn ṣalaye pe ti wọn ba ṣaaji mọto naa de iwọn ọgọrun-un agbara ina ẹlẹntiriiki, mọto naa le maa lọ kaakiri fun wakati mẹwaa o din iṣẹju mẹẹẹdogun, o si le rin kilomita okoolenirinwo ati meji (422 km) ko too rẹ ẹ. To ba si ti rẹ ẹ, tabi ti agbara rẹ ti dinku, ti wọn ba tun ti ṣaaji rẹ pẹlu ina mọnamọna, yoo tun maa ṣiṣẹ lọ ni.

Akọkọ mọto ti wọn ko jade yii yoo bẹrẹ si i ṣiṣẹ lawọn oju ọna wa l’Ekoo, lati fi mọ bi iwulo ati iṣẹ rẹ yoo ṣe peye to, lẹyin eyi ni wọn yoo bẹrẹ si i ṣe ọpọ yanturu rẹ sode fun tita faraalu to ba fẹ.

Gomina ni ireti wa pe ti mọto ọhun ba ti bẹrẹ iṣẹ, yoo mu irọrun pupọ wa, yoo si mu adinku ba wahala to wa nidii awọn mọto to n lo epo bẹntiroolu. Yatọ siyẹn, iṣoro eefin ati biba atẹgun jẹ to n waye latari epo bẹntiroolu yoo dohun igbagbe.

Sanwo-Olu tun ṣeleri pe oun yoo satunṣe si ọna Ọjọọ si Badagry, lati le mu ki lilọ bibọ ọkọ ja geere si i lagbegbe naa, ko si le tubọ rọrun fawọn to maa ṣiṣẹ lawọn ẹka ileeṣẹ ọkọ naa.

Ni ipari, gomina ni pẹlu iṣẹlẹ yii, ireti wa pe awọn ileeṣẹ oriṣii ọkọ mi-in bii Toyota, Mazda, Nissan ati bẹẹ bẹẹ lọ naa yoo waa da ileeṣẹ to n to ẹya ara ọkọ ti yoo maa lo ina ẹlẹntiriiki pọ lorileede wa silẹ.

Leave a Reply