Mọwumi fi bileedi ge ọmọ orogun ẹ labẹ l’Abẹokuta, o lo ji ẹran jẹ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọmọwumi Ibrahim, iyaale ile ẹni ọdun mọkanlelọgbọn(31) ti bẹrẹ ẹwọn ọdun meji ati oṣu mẹfa ti kootu Majisreeti agba to wa l’Abẹokuta ju u si lọsẹ to kọja yii, lẹyin to fẹnu ara ẹ jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun fifi bileedi ge ọmọ orogun oun loju ara.

Obinrin yii ko ṣẹṣẹ maa fi bileedi ge ọmọ ti ko ju ọmọ ọdun marun-un naa lọ loju ara,o ti n ṣe bẹẹ tipẹ gẹgẹ bi ọmọdebinrin ti iya rẹ ko si lọdọ baba rẹ mọ naa ṣe ṣalaye.

Ọmọwumi funra ẹ ko jiyan, o ni ohun toun n tori ẹ fi bileedi ya ọmọ yii loju abẹ ko ju ti ẹran to maa n yọ jẹ ninu isaasun ọbẹ oun lọ.

Ṣaaju ni agbefọba, Abọlade Bukọnla, ti ṣalaye fun kootu pe agbegbe Adedọtun, l’Abẹokuta, nibi ti Mọwumi n gbe pẹlu ọkọ ati ọmọ ọkọ ẹ yii, lo ti huwa naa ninu oṣu keji, ọdun yii.

Agbefọba lo darukọ ọmọ naa pe Adeṣẹwa Jubril lo n jẹ, ọmọ ọdun marun-un pere si ni. O fi kun un pe bileedi ti orogun iya ẹ fi ya a loju ara gbẹyin naa da ọgbẹ si i lara pupọ, iwa yii si lodi sofin, bẹẹ lo si ni ijiya ninu pẹlu.

Nigba to n dahun ibeere ti wọn bi i pe ṣe o jẹbi ẹsun naa tabi bẹẹ kọ, olujẹjọ sọ pe oun jẹbi, nitori loootọ loun maa n fi bileedi ya ọmọ naa labẹ nigba toun ba fẹẹ ba a wi pe o yọ ẹran jẹ ninu ikoko ọbẹ oun.

Adajọ agba I.O Abudu to gbọ ẹjọ naa paṣẹ pe ki Ọmọwumi Ibrahim lọọ ṣẹwọn ọdun meji ati oṣu mẹfa lai ni owo itanran ninu rara.

Leave a Reply