Mr Latin, Ọdunlade Adekọla, Rose Odika di apaṣẹ ẹgbẹ awọn oṣere (TAMPAN) 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbajugbaja oṣere nni, Bọlaji Amuṣan, ẹni ti gbogbo aye mọ si Mr Latin, ti di aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata lorileede yii, iyẹn Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (TAMPAN) fun saa keji.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jawe olubori ninu idibo ẹgbẹ awọn oṣere to waye n’Ibadan lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.

Yeye Rose Odika to ṣẹṣẹ fipo gomina ẹgbẹ TAMPAN ipinlẹ Ọyọ silẹ lo jawe olubori gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ẹgbẹ naa, nigba ti Ayọ Ọlabiyi (Bọbọ B) fagba han akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ dije gẹgẹ bii akọwe apapọ ẹgbẹ.

Awọn to tun jawe olubori fun ipo mi-in lọlọkan-o-jọkan, ti wọn yoo si maa ṣejọba ẹgbẹ awọn oṣere nilẹ yii pẹlu Mr Latin ni Ọdunlade Adekọla gẹgẹ bii oludari iṣẹ gbogbo to jẹ mọ Fidio; Banji Adelusi (Alukoro); Ayọ Ọladapọ (Alamoojuto eto iṣuna); Toyọsi Adesanya (Olootu eto ariya) Suleiman Ayọdeji (Akapo) ati Niyi Adebayọ to jẹ oludari iṣẹ sinima agbelewo.

Awọn yooku ni Ṣọla Kosọkọ, ọmọ bibi inu Jide Kosọkọ, to ti figba kan jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere nilẹ yii, ANTP nigba kan ri, gẹgẹ bii atọpinpin eto iṣuna; Sunday Oshibata (Igbakeji Akọwe ẹgbẹ); Damọla Ọlatunji (Alakooso eto iwadii) ati Akeem Alimi (Alakooso eto ọrọ-aje ẹgbẹ). Anthony Ogundimu loludari eto aabo nigba ti Temitọpẹ Faturoti jẹ igbakeji rẹ.

Pẹlu abajade eto idibo to lọ wọọrọwọ yii, awọn irawọ oṣere tiata bii Mr Latin, Ọdunlade Adekọla, Rose Odika, Ṣọla Kosọkọ ti i ṣe ọmọ Jide Kosọkọ, Bọbọ B ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn yoo maa tukọ iṣakoso ẹgbẹ TAMPAN lati asiko yii di ọdun 2026.

Leave a Reply