Faith Adebọla, Eko
Ilu-mọ-ọn-ka adẹrin-in poṣonu onitiata ilẹ wa nni, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Misita Makaroni ti sọ pe inu oun ko dun si iwa tawọn oṣere tiata ilẹ wa kan n hu, paapaa latigba ti ọrọ iwọde ta ko awọn ọlọpaa SARS ti waye lọdun to kọja titi dasiko yii, o ni alaiṣootọ ati alabosi lawọn oṣere kan, awọn oṣere naa si mọ ara wọn, tori owo ati anfaani ti wọn n ri gba lọdọ ijọba ko jẹ ki wọn le lanu ‘sọrọ soke’ lasiko yii nipa iwọde ayajọ EndSARS tawọn ọdọ kan fẹẹ gun le lọdun yii.
Debọ, toun naa kopa to jọju lasiko iwọde EndSARS ọdun 2020 ọhun fi aidunnu rẹ han lori ikanni instagiraamu rẹ, nibi to kọ ọrọ lẹkun-un-rẹrẹ si lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lori iwọde naa.
Mista Makaroni sọ pe:
“Mo fẹẹ sọ ohun to n dun mi lọkan. O ti di ọdun kan bayii ti iwọde EndSARS ṣẹlẹ. Gbogbo igba tawọn eeyan ba ti lawọn fẹẹ ṣe iwọde to jẹ mọ EndSARS l’Ekoo, niṣe lawọn ọlọpaa maa ko ọkọ wọn jade, awọn ọkọ akọtami ati eyi ti wọn fi n ja ni wọn maa gbe dina kaakiri ilu. Bẹẹ ilu Eko yii kan naa ti awọn ole n jale lọsan gangan ti ko sẹni to maa gbeja wọn ni o.
Ogunjọ, oṣu kẹwaa, lo de tan yii, a laa fẹẹ ṣe ṣewọde wọọrọwọ lọ si Too-geeti, wọn ni ko saaye, a tun laa fẹẹ ṣe apero ni gbọngan Landmark Summit Center, ka le jiroro laarin ara wa lai si ariwo, awọn alagbara kan tun bẹrẹ si i halẹ mọ wọn, titi tawọn alaṣẹ gbọngan naa fi sọ pe ko saaye fun apero wa mọ, ko sẹni to le da wọn lẹbi o, wọn aa ṣaa daabo bo ara wọn, okoowo wọn ati awọn kọsitọma.
Ṣugbọn ibeere mi ni pe, ṣe awọn ọdọ Naijiria o waa le kora jọ lati jiroro ọna itẹsiwaju laarin ara wọn mọ ni? O daa, ṣe ẹyin lẹ fẹẹ maa ṣakoso titi aye ni, abi?
Ijọba Eko dana ayẹyẹ nirọlẹ yii, awọn gbajumọ oṣere ti debẹ lọọ ṣere fun wọn. Ijọba Eko le ṣeto ayẹyẹ ṣaaju October 20, ṣugbọn wọn lawọn mi-in ko le kora jọ lati jiroro lalaafia, wọn ni niṣe lawọn kan maa dabaru ipade naa mọ wa lọwọ. Bawo waa lawọn ṣe n ṣe eto apero ati ayẹyẹ tiwọn ti ko sẹni to dabaru ẹ mọ wọn lọwọ to fi waa jẹ tiwa lawọn kan maa dabaru?
Ṣe ẹ ri i, ni ti awọn oṣere to kopa wọnyẹn, ẹ jẹ ka ba ara wa sọrọ, ijọba o daa, ijọba o daa, ṣugbọn ẹ n gbowo ijọba. Mi o ni kẹnikẹni maa ṣe jẹun jẹun o, ṣugbọn awọn nnkan to ju owo lọ wa. To ba jẹ ijọba to n tọju araalu ni, iba tiẹ daa, oju n pọn araalu, awọn onṣejọba yii o si ṣe nnkan kan lori ẹ.
Lọjọsi tawọn ọlọpaa mu mi, wọn lu mi pẹlu awọn to ku ti wọn mu, wọn ja wa sihooho, wọn n bi wa pe ‘ṣebi awa la n yọ gomina lẹnu, abi,’ ṣe iru ijọba bẹẹ lemi maa bọwọ fun?
Ti wọn ba maa ṣewọde ni October 20, emi o sa o, ṣugbọn o gbọdọ jẹ gbogbo wa ni. Ko saburu nibẹ ti wọn ba lọ si ayẹyẹ tijọba, ti wọn si wa si apero awa ọdọ, ta a tun jọ ṣewọde. Omi agbọn dun, ṣugbọn ko sẹni to fẹ ki wọn fọ agbọn lori oun. Tori ni Naijiria, teeyan ba tiẹ gba ki wọn fọ agbọn lori oun, ijọba o ni i jẹ kawọn eeyan ri omi agbọn ọhun mu. Gbogbo wa gbọdọ jọ ṣe ni o.”
Bẹẹ ni Mista Makaroni sọ.