Mr Macaroni rọ awọn ọmọ Naijiria lati dan ẹgbẹ oṣelu mi-in wo yatọ si APC ati PDP

Monisọla Saka

‘‘Ko le si ayipada rere kan bayii fun Naijiria, ta a ba ti yee paarọ awọn olori lati PDP si APC, bii ẹni paarọ aṣọ.’’
Gbajugbaja adẹrin-in-poṣonu nni, Debo Adedayọ ti ọpọ eeyan mọ si Mr Macaroni lo sọrọ yii di mimọ lori ẹrọ alatagba Twitter. O sọ pe oun ko le ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu to wa lori aleefa yii, APC ati PDP to jẹ ẹgbẹ alatako.
Ọkunrin alawada yii sọ ọ di mimọ pe onikaluku lo lẹtọọ lati ṣe ẹgbẹ oṣelu to ba wu u, bẹẹ lo tun fi kun un pe oun yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in, oun si gbagbọ pe awọn naa yoo pada goke.
Ninu awọn ọrọ to kọ sori ẹrọ alatagba ‘Twitter’ rẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lo ti ṣalaye pe, ayipada rere o le ba orilẹ-ede yii gẹgẹ bawọn eeyan ṣe n poungbẹ rẹ tawọn eeyan wa o ba yee paarọ awọn adari wa lati PDP si APC.
Gẹgẹ bo ṣe kọ ọ sori ẹrọ ayelujara, o ni, “Ẹnikẹni lo lẹtọọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba fẹ, mi o le ṣe ẹgbẹ APC tabi PDP laelae. Gbogbo eebu tẹ ẹ ba ri ni ki ẹ bu mi, ohun ti mo fẹ ni mo sọ yẹn”.
“Ma a kuku yaa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in, mo si nigbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu ọhun naa yoo di igi araba nla lọjọ kan. Ta a ba fẹ ki nnkan yipada, ipilẹ la gbọdọ ṣatunṣe si!
Gbogbo ohun temi ti maa n duro le lori ree, mo si ti sọ ọ laimọye igba. Ta a ba fẹ ki nnkan yipada si daadaa, a a kan le maa poyi loju kan naa bii omi inu ẹku”.

Nigba to n pe awọn eeyan lati ja ara wọn gba lọwọ awọn adari wa ti ko fẹ nnkan an ṣe yii, o ni, “Nigba to ba su onikaluku, ẹ jẹ ki koowa wa lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in, ka si gba orilẹ-ede wa pada lọwọ awọn to ti n ṣejọba le wa lori lati aimọye ọdun.
” Ẹ ma wo ti awọn to n bẹnu atẹ lu ọrọ ẹgbẹ oṣelu tuntun o. Loootọ, ki i ṣe ohun to le rọrun lati ṣe, bẹẹ ni ki i ṣe lẹẹkan naa ni a le ri ijọba gba lọwọ wọn, ṣugbọn ibi kan naa la ti gbọdọ bẹrẹ. Ko si ohun to le da awọn eniyan duro, ti iṣọkan ba ti wa laarin wọn”.

Leave a Reply