Muhammadu to fipa ba ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ n’Ilọrin ni iṣẹ eṣu ni

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Afurasi kan, Muhammadu Mailemu, to n gbe laduugbo Banni, lagbegbe Sango, niluu Ilọrin, ẹni tọwọ tẹ lasiko to ki ọmọ ọdun mẹwaaa kan mọlẹ ninu oko, to si fipá ba a lo pọ ni oun ko mọ ọn mọ ṣe e, eṣu lo ti oun lati ṣe ohun toun ṣe.

Ọkunrin naa ti wa ni ahaamọ olu ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ẹka tipinlẹ Kwara bayii, nibi to ti n kabaamọ ohun to ṣe.

Alukoro ajọ NSCDC nipinlẹ Kwara, SC. Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe baba ọmọ naa, Usman Mojana, to n gbe ni Gaa Mojana, ni Banni, lo fi iṣẹlẹ naa to olu ileeṣẹ awọn leti lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii.

Gẹgẹ bi alaye ti ọmọ naa ṣe fawọn agbofinro, o ni asiko toun wa ninu oko pẹlu aburo oun kan tiyẹn jẹ ọmọ ọdun mẹfa, toun si wa lori igi, nibi toun ti n ka iru, ni afurasi naa ṣadeede de, to si paṣẹ foun lati bọ silẹ.

O ni boun ṣe bọ silẹ lo ra oun mu, oju ẹsẹ ni aburo oun ti fere ge e. Ṣe lo ni Muhammadu bọ aṣọ ati awọtẹlẹ oun, to si fipa ba oun sun.

Ọmọ naa ṣalaye siwaju pe Sheu Garba to gbọ igbe oun lo waa gba oun silẹ lọwọ afurasi naa. Onitọhun lo kegbajare sawọn eeyan, ti wọn si mu ọkunrin naa, wọn wọ ọ de tesan ileeṣẹ NSCDC.

Afọlabi sọ pe ileeṣẹ awọn gbe ọmọ naa lọ silewosan ijọba to wa ni Banni fun ayẹwo, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ wọn ti ja ibale ọmọ naa ni tipa.

Ọgbẹni Ṣheu Garba to doola ọmọ naa fidi ẹ mulẹ pe loootọ loun ba afurasi naa lori ọmọ yii lasiko toun debẹ.

Alukoro NSCDC ni awọn obi ọmọ naa lawọn ko ṣe ẹjọ, ṣugbọn ohun tawọn n fẹ ni pe ki afurasi naa tọju ọmọ awọn, ko si san gbogbo owo itọju rẹ nilewosan.

Afọlabi ni lẹyin ti wọn tọju ọmọ naa tan, awọn mọlẹbi afurasi san gbogbo owo itọju rẹ. Ṣugbọn awọn obi ọmọbinrin naa kọ lati yọju si agọ NSCDC nitori ibẹru pe o ṣee ṣe ki wọn fipa gbe ẹjọ naa lọ si kootu.

O ni afurasi naa ṣi wa lahaamọ awọn, ṣugbọn awọn maa ranṣẹ pe obi ọmọ yii lati waa tọwọ bọwe pe wọn ko ṣe ẹjọ tabi kawọn gbe ẹjọ naa lọ sile-ẹjọ.

 

 

Leave a Reply