Faith Adebọla
Ara meriyiri lọrọ naa jẹ fawọn to gbọ ọ, atawọn to ka atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa nipa ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta kan, Mohammed Alfa, to yọ ọbẹ siyawo ẹ, Hamsatu Mohammed, ẹni ogoji ọdun, lọjọ ọdun tuntun, to si gun un pa.
Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, DSP Suleiman Nguroje, fi sita sọ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi ọdaran naa, wọn si ti fẹsun ipaniyan kan an.
O ni ọjọ ki-in-ni, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022 yii, niṣẹlẹ buruku naa waye labule Lande B, nijọba ibilẹ Gombi, nipinlẹ Adamawa, ọjọ naa si lọwọ tẹ afurasi ọdaran naa.
Alukoro ọlọpaa ṣalaye pe iwadii fihan pe aawọ kan lo bẹ silẹ lọjọ ọdun naa, ariyanjiyan naa si da lori ẹsun ti ọkọọyawo yii fi kan iyawo rẹ, o lo ko kuro lọọdẹ oun lai sọ foun, o ko lọ sile ara ẹ lai jẹ koun mọ si i.
Wọn lọkọ yii tun fẹsun kan oloogbe naa pe o yọ lara paanu orule ile oun, o lọọ fi pari ile tiẹ, o ni iwa ọjale-onile-bo-tiẹ-lẹyin niyawo oun hu yẹn, lọrọ ba di ran-n-to.
Ibi ti wọn ti n ṣe gbọnmi-si-i-omi-o-to ọrọ ọhun ni ọkọ ti fa ibinu yọ, o ki ọbẹ aṣooro mọlẹ, lo ba gun iyawo ẹ pa.
Oju-ẹsẹ ni wọn lobinrin naa ti ṣubu lulẹ, kawọn aladuugbo si too gbe e digbadigba dele iwosan aladaani kan nitosi ibẹ, niṣe lawọn dokita sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa ti ku.
Olori abule tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, Ọgbẹni Jauro Babangida Boka, lo ta awọn agbofinro lolobo ọrọ naa ti wọn fi ran ikọ ọlọpaa wa sibẹ, ti wọn si fidi ẹ mulẹ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye.
Lẹyin eyi ni wọn dọdẹ Muhammed, ọwọ ba a, wọn si fi pampẹ ofin gbe e lọ sagọọ wọn.
Alukoro ọlọpaa ni Kọmiṣanna awọn, CP Mohammed Ahmed Barde, ti gbọ siṣẹlẹ yii, o si ti ni ki wọn fi afurasi ọdaran yii ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to n tọpinpin iwa ọdaran abẹle nipinlẹ ọhun, o ṣekilọ pe kawọn to fẹran lati maa gbẹsan lọwọ ara wọn tete lọọ kọwọ ọmọ wọn bọṣọ tori sẹria to gbopọn lo n duro de iru wọn niwaju adajọ gẹgẹ bi ofin ṣe wi.