Muhammed, ọmọ Fulani, to n da awọn eeyan lọna labule Agbagi ti bọ sọwọ ọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Muhammed Altine lorukọ ọkunrin pupa yii, ọkan ninu awọn Fulani to maa n da awọn ara abule Agbagi, nipinlẹ Ogun, lọna ni, ṣugbọn ọwọ ti tẹ ẹ bayii, o si ti wa lahaamọ ni Eleweeran.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii, ni aṣiri Muhammed Altine tu, lẹyin ti oun atawọn mẹta kan da agbẹ kan torukọ ẹ n jẹ Ajao Moses lọna, nigba tiyẹn n bọ lati oko.

Moses sọ fawọn ọlọpaa pe ori ọkada oun loun wa, toun n lọ sile lati oko. Ojiji ni awọn mẹrin kan yọ soun pẹlu ada ati igi, o ni wọn re oun bọ lori ọkada, wọn si fẹrẹ lu oun pa.

Ẹgbẹrun lọna aadọta naira (50,000) lo ni o wa lapo oun lọjọ naa, o ni awọn to kọ lu oun gba owo naa lọwọ oun ki wọn too fi oun silẹ, ti wọn wọgbo lọ.

Tesan ọlọpaa Ilupeju lo ti fẹjọ ọhun sun, DPO ibẹ si ko awọn ikọ rẹ lẹyin, wọn wọnu igbo ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lọ. Muhammed Altine yii nikan ni wọn ri mu, bo tilẹ jẹ pe o sọ fun wọn pe mẹrin ni awọn, awọn yooku rẹ ti na papa bora lapa ibomi-in.

Awọn ọlọpaa ṣi n wa awọn yooku rẹ to sa lọ naa, ṣugbọn ọmọ tọwọ ba yii ṣi wa nibi ti wọn fi i si ni tiẹ, to n wo horohoro.

Leave a Reply