Mutairu ati Wasiu si tan ọmọbinrin kan lati Eko lọ s’Ibadan, lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn ge ori ẹ

Jọkẹ Amọri

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lawọn ọlọpaa ṣafihan awọn afiniṣowo meji kan, Ismaila Wasiu, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ati Mutairu Shittu, ẹni ọdun marundinlogoji, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Ọmọbinrin kan torukọ rẹ n jẹ Mujidat, ni wọn tan lati ilu Eko lọ si Ibadan, wọn si pa a. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn kun ẹya ara rẹ bii ẹran, ọwọ wọn lawọn agbofinro si ti ba ori ọmọbinrin naa ati gbogbo ẹya ara rẹ ti wọn ti ge ni baasi baasi.

Nigba to n ṣafihan wọn niluu Ibadan, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ, ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn kan ni wọn ṣe alami fawọn lati Ayekalẹ, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, ni nnkan bii aago meji aabọ ọjọ ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe awọn ri ori eeyan lọwọ Ismaila Wasiu ati Mutairu Shittu

Eyi lo ni o mu ki awọn ọlọpaa lati ilu Saki bẹrẹ iwadii wọn, ko si pẹ rara tọwọ fi tẹ awọn mejeeji pẹlu ori tutu ati ẹya ara eeyan ti wọn ti kun bii ẹran to jẹ ti ọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Mujidat.

A gbọ pe niṣe ni wọn pe ọmọbinrin naa to jẹ ọrẹbinrin ọkan ninu wọn lori foonu pe ko waa pade awọn n’Ibadan. Nigba to si de ọdọ wọn naa ni wọn pa a. Oogun owo la gbọ pe wọn fẹẹ fi ẹya ara ọmọbinrin na ṣe ti wọn tori rẹ pa a. Oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ ati ẹya ara ọmọbinrin yii lawọn ọlọpaa ka mọ wọn lọwọ.

Alukoro ọlọpaa ni wọn ti gbe ẹya ara ti wọn gba lọwọ wọn naa lọ si ile igbokuu-si, ti iwadii to gbopọn si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply