Mutiu Ajamajẹbi ti jẹbi o, ole lo ja ti wọn fi sọ ọ si atimọle ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun  

Tọsidee, Ọjọbọ, to kọja yii, ni wọn wọ afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Mutiu Ajamajẹbi, lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa laduugbo Idi Araba, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, latari ẹsun ole jija. Agbefọba, Inspẹkitọ Abdulmumuni Jimba, sọ nile-ẹjọ pe deede aago mejila ọsan Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, lọwọ tẹ odaran naa l’abule Ajelanwa, loju ọna to lọ si odo Okerete, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, nibi to ti ji pako ikọle to to ogoji, tiye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogoje naira (#140.000), bẹẹ Ọgbẹni Salimọnu Adegoke lo lawọn igi naa.

Bo tilẹ jẹ pe ariyanjiyan bẹ silẹ laarin agbẹjọro Ọgbẹni Salimọnu ati Inspẹkitọ Jimba ati agbẹjọro olujẹjọ, Lọọya K. A. Adegoke, lori iye owo ti igi kọọkan to, Lọọya Adegoke fi ye ile-ẹjọ pe igi ikọle kọọkan ninu ọja ko to iye ti agbefọba sọ nile-ẹjọ, ṣugbọn agbefọba jẹ ko di mimọ pe olujẹjọ labẹ ofin lẹtọọ lati fi kun owo ọja rẹ, o ku sọwọ onraja lati dunaa dura lori ọja to fẹẹ ra.

Nigba ti adajọ pe olujẹjọ naa lati sọ ero rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, afurasi ọhun loun ko jẹbi.

Adajọ I. O. Uthman ni idajọ kootu naa lo maa sọ boya o jẹbi tabi ko jẹbi. O loun faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro meji ti wọn jẹ ọmọ ilu Ṣaki, ti wọn tun niṣẹ gidi lọwọ, ti ile wọn ko si fi bẹẹ jinna sayiika kootu ọhun.

O ni o di dandan fun irufẹ oniduuro bẹẹ lati mu afurasi ọdaran naa de ile-ẹjọ nigbakuugba ti igbẹjọ ba fẹẹ waye, aijẹ bẹẹ, ki wọn da afurasi naa pada sahaamọ ọlọpaa, lo ba sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.

 

 

 

Leave a Reply