Muyideen atọrẹ ẹ ji tẹgbọn-taburo gbe, inu igbo ti wọn so wọn mọ ni wọn ku si l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Usman Muyideen ati Isa Memudu lori ẹsun pe wọn ji awọn ọmọdekunrin meji gbe, wọn si pa wọn nipakupa niluu Oṣogbo.

Muyideen lo jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun, nigba ti Memudu jẹ ọmọ ogun ọdun.

Nigba ti Kọmisanna funleeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọse yii, o ni lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn ji awọn ọmọ mejeeji naa; Thompson Onibokun, ọmọ ọdun mẹtala ati Samson Onibokun, ọmọ ọdun mejila gbe.

Ọlọkọde ṣalaye pe lopopona Durojaye, ni Zone 8, agbegbe Iludun, niluu Oṣogbo, ni wọn ti ji wọn gbe, nigba ti ọwọ si tẹ Muyideen lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, lo jẹwọ ibi ti wọn ko awọn ọmọ naa pamọ si ninu igbo kan lagbegbe Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo.

O ni oku awọn ọmọ mejeeji naa ni wọn ba ninu igbo ọhun, wọn si ti gbe wọn lọ sile igbokuupamọ-si tileewosan State University Teaching Hospital, Oṣogbo, fun ayẹwo.

ALAROYE ba Muyideen sọrọ lori idi to fi huwa naa, o ni Ipele keji nileewe Kwara State University loun wa, kekere loun si ti mọ Memudu to jẹ Fulani nitori pe adugbo kan naa lawọn jọ n gbe. O ni Memudu lo mu imọran wa pe kawọn ji awọn ọmọ mejeeji gbe, niwọn igba to si jẹ pe ọmọ iyawo ẹgbọn oun ni Samson, o rọrun fun oun lati ko wọn.

“A lọ sibi ti wọn ti n gba bọọlu nirọlẹ ọjọ yẹn, mo si sọ fun wọn pe mo fẹẹ lọọ ra nnkan fun wọn, ki wọn tẹle mi. Emi ati Memudu ko awọn mejeeji sori ọkada, nigba to ku diẹ ka de agbegbe Koka, a sọ pe ki ọlọkada duro, a si sọkalẹ.

“Bayii la ko wọn wọnu igbo, a si fi okun de wọn lọwọ-lẹsẹ mọ ara igi. Nigba ti a n de wọn, wọn beere lọwọ mi pe ki ni mo fẹẹ fi awọn ṣe, mo sọ pe ki wọn ma ṣeyọnu, mo maa pada waa tu wọn silẹ. Mo pe nọmba Baba Thompson pe ti wọn ba nifẹẹ ẹmi awọn ọmọ mejeeji, ki wọn tete wa miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira wa laaarin ọjọ meje.

“Burẹdi ati ọti ẹlẹridodo la n fun wọn jẹ ni gbogbo igba ti wọn fi wa lọdọ wa, ko si si ẹnikẹni to fura si mi ninu mọlẹbi tabi laarin adugbo wa pe emi ni mo huwa naa. Bi a ṣe denu igbo yẹn lọjọ kẹrin la ri i pe awọn ọmọ mejeeji ti ku, bayii la fi wọn sibẹ, ti a si pada sile.

“Inu ile ni mo wa ti awọn ọlọpaa fi fi foonu ti mo fi pe Baba Thompson ṣawari ibi ti mo wa, ti wọn si waa gbe emi ati Memudu. N ko ṣeru rẹ ri, Mẹmudu lo fun mi nimọran. Mo kan fẹẹ bẹ awọn obi wọn pe ki wọn jọwọ, foriji mi”

Ni ti Memudu, o ni oun ko huwa ijinigbe ri. O ni iṣẹ igbẹ-didẹ ati mẹkaniiki loun n ṣe, ṣe loun kan fọpọlọ gbe ero naa kalẹ nitori oun nilo owo lati fi bẹrẹ okoowo kan toun fẹẹ ṣe.

Amọ ṣa, Ọlọkọde ti sọ pe ni kete tiwadii ba ti pari lawọn mejeeji yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply