N ko ti i mọ oludije fun’po gomina Ọṣun lọdun to n bọ, ṣugbọn mo mọ pe ẹgbẹ wa maa wọle pada – Bisi Akande

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga akọkọ fun ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, Oloye Bisi Akande, ti sọ pe oun ko ti i le sọ ni pato pe ẹni bayii ni yoo dije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun to n bọ, ṣugbọn ohun kan to daju ni pe, ẹgbẹ naa yoo rọwọ mu.

Akande, ẹni to ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ naa sọrọ idaniloju yii lasiko ti igbimọ agba Ọṣun n gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle nile rẹ to wa niluu Ila.

Awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ti wọn gba ọhun ni Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Dokita Yẹmi Farounbi, Ọjọgbọn Derẹmi Abubakre ati Sẹnetọ Ajibọla Baṣiru to jẹ agbẹnusọ fun awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba lorileede yii.

Oloye Akande sọ pe ki awọn eeyan fọkanbalẹ lori wahala keekeeke to n waye lọwọlọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, nitori awọn n ṣiṣẹ gidigidi lati yanju ẹ.

O ni gbogbo wahala naa ni yoo yanju ko too di asiko idibo nitori oniruuru ijọba ibilẹ lawọn ọmọ Igbimọ Agba Ọṣun ti wa, onikaluku yoo si pada sile lati ta awọn ọmọ ẹgbẹ ji lọtun.

Ni ti idibo aarẹ orileede yii, Oloye Akande ṣalaye pe ko si ofin kankan to sọrọ nipa pipin ipo ninu ẹgbẹ oṣelu APC, awọn eeyan iha Guusu si ti ṣetan lati koju awọn ti iha Ariwa, ẹnikẹni ti ẹgbẹ ba si fa kalẹ ni yoo di aarẹ Naijiria.

Ninu ọrọ ti alaga ẹgbẹ Igbimọ Agba Ọṣun, Oloye Ṣọla Akinwumi, o ni erongba igbimọ naa ni lati ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun forukọsilẹ fun kaadi idibo, ki wọn si ṣe ojuṣe wọn lasiko idibo gomina lọdun 2022.

O ni ko si ẹgbẹ oṣelu kankan to ni iru awọn eeyan ja-n-kan-ja-n-kan ti awọn ni nipinlẹ Ọṣun, ko si ṣee ṣe ki ẹgbẹ naa fidi-rẹmi ninu idibo naa.

O fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ wa labẹnu ti ẹnikẹni ti inu ba n bi laarin wa le gbe lati fi aidunnu rẹ han nitori awọn ko fẹ ohunkohun to le fa iyapa ninu ẹgbẹ naa.

O ni asiko ti to fun ẹnikẹni ti inu ba n bi lati bu omi suuru mu, nitori ko si abuja kankan lọrun ọpẹ, ẹgbẹ APC nikan lo le rọwọ mu lọdun to n bọ l’Ọṣun.

Ni ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla, Akinwumi sọ pe ko lee ṣe ohunkohun ti yoo ta ko itẹsiwaju ẹgbẹ naa l’Ọṣun nitori ara ọmọ Igbimọ Agba ẹgbẹ APC ni.

Leave a Reply