Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ to n ri si ọrọ ounjẹ ati oogun nilẹ yii (NAFDAC), ti rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati maa ṣọra pẹlu awọn ounjẹ tabi oogun ti wọn yoo maa lo lasiko yii, nitori o lewu fun ilera, paapaa ju lọ epo pupa, nitori ayederu epo pupa ti gbode.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni ọga agba fun ajọ naa nilẹ yii, Ọjọgbọn Mojisola Adeyẹye, ṣe ikilọ yii niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, lasiko ilanilọyẹ ti wọn ṣe fun ẹkun Aarin Gbungbun Ariwa orile-ede yii to waye niluu Ilọrin, nigba to gbe ilanilọyẹ naa lọ si awọn ọja nla kan niluu Ilọrin, o ni ero ajọ naa ni lati daabo bo ọmọ Naijiria lori bi awọn ayederu ohun eelo ipese ounjẹ ṣe gba igboro. O tẹsiwaju pe ọpọ awọn onisowo to n ta ọja lawọn ọja gbogbo ni ko naani ilera araalu, bi wọn yoo ṣe jere rẹpẹtẹ lo jẹ wọn logun, eyi lo mu ki wọn maa po aro papọ mọ epo pupa ko le pọ daadaa.
O fi kun un pe ọpọ lo maa n fi majele (sniper) sinu ẹwa, ẹja ati ẹran ko le pa kokoro to wa lara ounjẹ wọn yii, ti iru ounjẹ bẹẹ si lewu fun ẹni to ba jẹ ẹ lọjọ iwaju. Bakan naa lo tun gba awọn iyalọja nimọran lati maa ṣamulo gbogbo eroja to yẹ lati dena arun Korona lawọn ọja wọn gbogbo.