Naijiria nikan kọ lounjẹ ti gbowo lori, o wọn l’Amẹrika ati UK naa – Lai Mohammed

Faith Adebọla

 Ijọba Naijiria ti sọ pe ẹtan lasan lo wa nidii bawọn eeyan ṣe n fi ounjẹ to gbowo leri tabi bẹntiroolu to wọn lasiko iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari wera pẹlu ti awọn alakooso to ti kọja sẹyin, wọn ni orileede yii nikan kọ ni nnkan ti n gbowo leri, o n ṣẹlẹ l’Amẹrika ati UK naa.

Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Mohammed, lo sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja.

Alaaji Lai bẹnu atẹ lu bawọn oniroyin kan, ati araalu ṣe n tẹnu mọ ọrọ ounjẹ to wọn ati iṣoro epo bẹntiroolu bii ẹni pe Naijiria nikan ni iru ẹ ti n ṣẹlẹ, o lọrọ to kan gbogbo orileede agbaye ni.

Minisita naa sọ pe “Ẹ jẹ ki n sọrọ lori bi awọn oniroyin kan ati awọn eeyan ti o gba tiwa ṣe n ṣe ifiwera iye ti wọn n ta ọja, iye ti wọn n ta epo bẹntiroolu ati disu, iye ti wọn n ta ounjẹ lọdun 2015 ka too dori aleefa ati iye ti wọn n ta a bayii.

“Awọn ifiwera ti wọn n ṣe wọnyi, ẹtan ni. Awọn ti wọn n ṣe ifiwera naa ko loootọ daadaa. Ẹ jẹ ka fi ti ounjẹ ati bẹntiroolu ṣakawe. Ẹ lọọ ṣewadii iye ti wọn n ta awọn ounjẹ lawọn orileede mi-in kari aye lori ikanni gọgu (Google), paapaa lorileede Amẹrika ati UK (United Kingdom), ẹ maa ri i pe awọn nnkan gbowo lori nibẹ naa, bo tilẹ jẹ pe bẹntiroolu ati gaasi wọn ko lọ soke. Ohun ta a n sọ ni pe ọrọ ọja to gbowo leri, kari aye ni, ibi gbogbo ni wọn ti n ko adiẹ alẹ ni. Ki i ṣe Naijiria wa nikan.

Tori naa, ko daa bi wọn ṣe n sọrọ bii pe iṣoro Naijiria ni ọja to wọn, ailoye ati ẹtan niyẹn.

Mo si fẹẹ sọ fun yin pe ọrọ epo bẹntiroolu to wọn laipẹ yii ti n rọju bọ diẹ diẹ, o maa kasẹ nilẹ ti awọn eto tijọba ṣe ba ti fẹsẹ mulẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, lati ibẹrẹ oṣu Keji, ọdun yii, ni iṣoro ọwọngogo epo bẹntiroolu ti gbode latari bi wọn ṣe ni epo bẹntiroolu ti ko sunwọn kan ni wọn ko wọlu, eyi lo si fa akoba fawọn mọto ati ẹrọ, ṣugbọn titi dasiko yii, owo epo naa ko ti i pada si bo ṣe wa tẹlẹ lọpọ agbegbe yika ilẹ wa.

Leave a Reply