Naijiria wa lara orilẹ-ede to n fun Singapore lounjẹ, to n fun wọn laṣọ, ki nnkan too yiwọ fun wa-Akintọla

Aderounmu Kazeem

Gbajugbaja nla nidii iṣẹ ofin, Amofin-Agba Akintọla Adeniyi ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe Naijiria ko ti i si ni ipo to yẹ ko wa pẹlu ba a ṣe pe ọdun mọkanlelọgọta laipẹ yii, o ni sibẹ, o yẹ ka maa dupẹ ni nitori ki i ṣe pe o kuku bajẹ fun orileede wa patapata. O sọrọ naa ninu ifọrọ kan to ṣe pẹlu akọroyin ALAROYE lo ti sọrọ naa

O sọ pe ‘‘Ti a ba ni ki a wo ọdun ti a ti gba ominira, paapaa lori boya ki a maa dunnu pe ọdun naa ti pẹ, oju meji ni a gbọdọ fi wo o, nitori ọrọ ọhun bii igba ti a ba sọ pe ohun to kọju si ẹnikan ni, ẹyin lo maa kọ si ẹlomi-in.

‘‘Ni temi, o yẹ ka yọ, ka si dupẹ ibi ta a de loni-in, bo tilẹ jẹ pe a ko ti i delẹ ileri, a ṣi jinna sibẹ, ṣugbọn bibeli naa sọ pe ninu ohun gbogbo, a gbọdọ maa dupẹ fun Ọlọrun. Mo fẹ ka ranti pe awọn orilẹ-ede kan wa to jẹ pe wọn ṣẹṣe bọ loko ẹru ni, koda wọn ko ti i pe ọgbọn ọdun ti wọn bọ loko ẹru. Mi o fẹẹ maa daruko, bi wọn ti ṣe waa dagba to, sibẹ ko si ominira ọrọ aje fun wọn. Awa ti lọ sibẹ, a ri nnkan ti wọn n pe ni ominira ọrọ oṣelu ati ominira ọrọ aje. Awọn mejeeji yii ki i ṣe ọkan naa.

‘‘Iru awa ti wọn bi ni ọdun diẹ ṣaaju ominira le maa sọ nigba ta a bẹrẹ ileewe lọdun 1966, nnkan ko ri bayii, titi digba ta a wọ yunifasiti, ṣugbọn ẹ ma jẹ ki a gbagbe pe ibi kan la ti n bọ.

‘‘Ohun to baayan ninu jẹ ni pe ka ni awọn ologun ko ba gbajọba, ti wọn fi wa silẹ bi a ṣe n ba ijọba wa bọ ni apa Iwọ-Oorun, ijọba awọn Ọbafẹmi Awolọwọ, ti kaluku n ṣe ijọba ẹlẹkunjẹkun, awọn orilẹ-ede bii Singapore, South-Korea ni wọn iba jẹ akẹgbẹ fun ilẹ Yoruba. Ohun ibanujẹ lo jẹ nigba ti a lọ si orilẹ-ede South-Korea lọdun 2019, ti Aarẹ orilẹ-ede wọn ba wa sọrọ, iyẹn awa aṣoju orilẹ-ede lagbaye. Ninu ọrọ ẹ lo ti sọ itan ara wọn, njẹ ẹ le gbagbọ pe Naijiria wa lara orilẹ-ede to n fun wọn lounjẹ, to n fun wọn ni aṣọ, iyẹn aṣọ ti a ti wọku ni o.

‘‘Orilẹ-ede yii wa lara awọn orilẹ-ede agbaye to maa n fi ounjẹ ati aṣọ ranṣẹ si wọn. Nigba naa lọhun-un, o lo buru fun awọn debii pe niṣe ni awọn obinrin awọn da yẹri eti wọn jọ, ti orilẹ-ede yẹn lọọ ta a lati fi ra ounjẹ.

‘‘Loni-in, ẹ o le pe iru orilẹ-ede yẹn ni ilu to wa ninu ipo kẹta ninu idagbasoke, iyẹn ipo ti awa wa loni-in. Wọn ti lọ jinna-jinna, bẹẹ la ṣiwaju wọn gba ominira, koda a tun fun wọn ni ẹbun. Amunkun ẹru ẹ wọ, o ni oke lẹ n wo, ẹ o wo isalẹ. Awọn ologun ti wọn ja ijọba gba mọ awọn Awolọwọ lọwọ ni wọn ba nnkan jẹ, paapaa fun ilẹ Yoruba.

‘‘Ni ti awa ọmọ kaaarọ-oo-jiire, ọpẹ lo yẹ ki awa maa du o, nitori ko sibi ti mi o ti i lọ ni gbogbo aye yii ti ọmọ eeyan n gbe. Ko wa sibi ti ẹ de ti ẹ o ti ni i ba ọmọ Yoruba. Ninu igbelewọn kan ti wọn ṣe ni ilu Houston, ni Texas, l’Amerika, wọn ni ti ẹ ba ri dokita alawọ dudu mẹjọ ni agbegbe yẹn, marun-un ninu wọn, ọmọ Yoruba ni. Eyi fidi ẹ mulẹ pe ninu ẹni to yẹ ki o maa dupẹ ni  iran Yoruba wa.

‘‘Ohun to fun wa ni anfaani yẹn ni pe eto ẹkọ ti awọn Awolọwọ gbe wa ran awọn Yoruba lọwọ pupọ.  Nigba kan to rẹ mi ti mo lọọ gba itọju ni South Africa, nibi ti mo ti n duro de dokita to maa tọju mi, ni mo ba ri patako kan ti wọn kọ orukọ awọn dokita si loriṣiiriṣii, ninu orukọ mọkanlelogoji to wa lara patako, mẹtadinlogun ninu wọn, ọmọ Naijira ni wọn, ọmọ Yoruba ni mẹrindinlogun ninu awọn mẹtadinlogun yẹn, ẹni kan yooku, Osagie lo n jẹ, awọn ẹya kan ti wọn tun fara pẹ wa diẹ ni. Nnkan ti mo n sọ yii, igbesẹ awọn aṣaaju wa lori ọrọ ẹkọ ti wọn ti sare gbe lọwọ lo jẹ ki a maa wa nipo aṣaaju.

‘‘Omi-in ti mo tun fẹẹ sọ ni ti Ọmọọba Ido-Ani, to ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣeru ẹ ri lagbaye. O ṣiṣẹ abẹ fun alaboyun, o gbe oyun inu ẹ jade, o ṣiṣe abẹ fun ọmọ yẹn, lẹyin ẹ lo da a pada, ti ati ọmọ ati iya si wa laaye. Iwuri nla ni lagbaaye, bẹẹ ni Aare orilẹ-ede America nigba yen, Donald Trump, kan sara nla si i, bo tilẹ jẹ pe awa ta a ni ọmọ to ṣe gudugudu meje yii ko tiẹ ṣe bii pe a gbọ si ohun meriiri to ṣe yẹn.

‘‘Gbogbo ẹ naa kọ lo bajẹ, awọn ologun naa gbiyanju nipa iṣẹ idagbasoke laarin ilu. Ẹ wo biriiji afara ẹlẹẹkẹta, iyẹn Third Mainland Bridge, awọn ni wọn ṣe e, gbogbo yunifasiti ta a ni yatọ sawọn to ti wa ki a too gba ominira, awọn ologun lo da wọn silẹ lasiko ti wọn fi wa nijọba. Ile ifọpo orilẹ-ede yii, yatọ si ẹyọ kan ti wọn ba nilẹ, awọn ni wọn kọ iyooku ta a ni, bi wọn ko tiẹ ṣiṣẹ mọ. Awọn naa ni wọn kọ ọ, awọn naa ni wọn ba a jẹ.

Ọna onibeji ta a maa kọkọ ni, awọn ologun yii naa ni wọn ṣe wọn, ti a ba waa n sọ nipa ọrọ Naijria, ohun ti a fi maa maa dunnu wa, bo tilẹ jẹ pe ibi to yẹ ki a wa kọ la wa loni-in.”

Leave a Reply