Naijiria yoo bọ ara wọn yo bi ida ọgbọn ba n dako – Ọladuni

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni Giiwa ileewe giga ti wọn ti n kẹkọọ nipa eto iṣẹ agbẹ niluu Ilọrin (ARMTI), Dokita Olufẹmi Ọladunni, ṣalaye pe ti ida ọgbọn ọmọ orileede yii ba n dako, ko ni i si iṣoro ọwọngogo ounjẹ mọ.

Ọladunni sọrọ naa di mimọ lasiko ti ileewe ọhun ṣe idanilẹkọọ fun ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Kwara, eyi to jẹ ọkan lara eto ẹgbẹ naa lati fi sami ayẹyẹ ọṣẹ akọroyin wọn ti ọdun yii, ti yoo gba wọn lọjọ mẹta gbako.

O tẹsiwaju pe oniṣẹ ijọba ni, oloṣelu tabi ipo yoowu ki eniyan di mu, ti gbogbo ọmọ Naijiria ba n gbinyaju oko dida, eyi yoo mu adinku ba ounjẹ to wọn bii oju, o ni ẹni to n ṣiṣẹ ijọba to n gbowo oṣu, to ba tun n dako, ko ni i maa fowo ra ounjẹ mọ.

Bakan naa lo tun rọ ijọba Naijiria lati faaye gba gbogbo olugbe orile-ede yii ki wọn maa dako, ki ijọba si din owo awọn eroja ti wọn fi n ṣiṣẹ oko, eyi ni yoo mu iṣẹ agbẹ wu tolori tẹlẹmu nilẹ yii.

Leave a Reply