Nana jira ẹ gbe N’Ifaki-Ekiti, lo ba n bere fun ẹgbẹrun lọna aadọta naira lọwọ ololufe rẹ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Sule Nana, ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii, nibi to ti n ṣalaye idi to fi ji ara rẹ gbe pamọ, to si n beere owo itanran lọwọ ololufẹ rẹ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutu,  ṣalaye pe ogunjọ, ọṣun kọkanla, ọdun 2021, ni awọn ọlọpaa sadeede gba ipe kan lati ọdọ ọmọdebinrin yii pe awọn ajinigbe ti ji oun gbe ni ọna to lọ lati Ifaki si ilu Ọyẹ-Ekiti.

Bakan naa ni obinrin yii tun pe ọkọ rẹ, to si fi to o leti pe awọn ajinigbe ti ji oun gbe, wọn si n beere fun ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ki oun too le gba itusilẹ.

Obinrin yii tun sọ fun ọkọ rẹ pe oun ati awọn ero ọkọ ni wọn ji gbe, ti wọn si wa ninu igbo kan ti oun ko mọ.

Abutu ni ipe yii lo fa a ti awọn ọlọpaa kogberegbe ti ẹka Rapid Respond Squad, ti ileeṣẹ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ṣe bẹrẹ itọpinpin lori ọrọ ijinigbe naa, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe ayẹwo si gbogbo igbo to wa laarin Ifaki si Ọyẹ-Ekiti.

Lẹyin itọpinpin yii ni wọn ri i pe obinrin yii ji ara ẹ gbe ni, to si fẹ fọgbọn gba owo lọwọ ololufẹ rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ.

Ṣugbọn lẹyin iwadii, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ Nana niluu Ifaki-Ekiti, ninu ile kan to gbe ara rẹ pama si.

Abutu sọ pe obinrin yii ti jẹwọ fawọn ọlọpaa, iwadii si n tẹsiwaju lori ọrọ naa.

Leave a Reply