NBC fofin de ileeṣẹ tẹlifiṣan mẹta, wọn ni wọn firoyin da wahala silẹ

Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto igbohun-safẹfẹ (NBC) ti fofin de ileeṣẹ tẹlifiṣan mẹta bayii, bẹẹ ni wọn ti ni ki wọn lọọ sanwọ itanran nla.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn lọwọ si bi rogbodiyan ṣe bẹ silẹ kaakiri orilẹ-ede yii nipasẹ iroyin ti wọn gbe.

Awọn ileeṣe ọhun ni; Arise TV, African Independent Television (AIT) ati Channels Television. Owo itanran ti wọn ni ki wọn san wa laarin miliọnu meji si mẹta naira.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe niṣe ni wọn lo iroyin ibi ti wọn ti n yinbọn, ti wọn si sọ pe Lẹkki lo ti ṣẹlẹ lai wadii ẹ daadaa ki wọn too gbe e sori afẹfẹ.

Wọn ni ohun tawọn eeyan ri gan-an ree ti awọn ọdo kan fi gbinaya, ti wọn bẹrẹ si i ba dukia jẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

 

Leave a Reply