NDLEA beere fun aṣẹ lati gbẹsẹ le dukia atawọn owo nla ti wọn ba lakaunti Kyari

Adewumi Adegoke

O da bii pe sinima ti ko ni i ṣe e wo tan lọrọ ọkunrin ọlọpaa ọmọ bibi ipinlẹ Borno to wa ni ẹka to n ri si ijinigbe ati iwa ọdaran to ba lagbara ju, Abba Kyari, pẹlu bi awọn aṣiri oriṣiiriṣii ṣe n tu nipa ọkunrin naa, ti ajọ to n wadii rẹ lọwọ bayii, NDLEA si ti n beere fun aṣẹ lati gbẹsẹ le gbogbo awọn dukia rẹ.

Laipẹ yii ni wọn kan owo nla kan to le ni biliọnu mẹrin Naira (4.2bn) ninu akaunti oun ati ọmọọsẹ rẹ kan, Sunday Ubua, gẹge bi iweeroyin Punch ṣe gbe e jade. Owo yii ni wọn lo ṣee ṣe ko jẹ eyi ti wọn ri lati ara oogun Tramadol kan ti wọn ni iye rẹ to biliọnu mẹta Naira ti wọn gbẹsẹ le, ti wọn ni wọn pada ta fun awọn mi-in.

ALAROYE gbọ pe owo to le ni biliọnu kan Naira (1.4bn) lo kọja sinu asuwọn Kyari lasiko to fi jẹ ọga to n mojuto awọn iwa ọdaran to ba lagbara ju (IRT).

Bakan naa ni wọn ba biliọnu mẹta o din diẹ (2.8bn) ninu asunwọn akaunti bii mẹjọ ti Ubua to jẹ igbakeji rẹ n lo.

Gẹgẹ bi iwadii awọn NDLEA, owo to le ni biliọnu meji Naira (2.664) ni wọn ni wọn san si akaunti Ubua ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2019. Ajọ to n gbogun ti oogun oloro yii gbagbọ pe owo ti wọn ri ninu asunwọn awọn eeyan naa ni i ṣe pẹlu awọn oogun oloro kan ti wọn ta, ninu eyi ti Tramadol wa.

Ṣe ajọ yii kuku ti bẹrẹ iwadii lori pe Kyari atawọn ọmọọṣẹ rẹ gbẹsẹ le oogun kan ti wọn n pe ni Tramadol nile ti wọn n ko ẹru si kan to wa ni Amuwo Ọdọfin, niluu Eko, eyi ti owo rẹ to biliọnu mẹta Naira.

Awọn ikọ Kyari gbẹsẹ le oogun yii, wọn si pada lọọ ta a fun awọn to n ṣiṣẹ gbigbe oogun oloro lẹyin ti wọn gbẹsẹ le e. Lasiko naa ni wọn ni owo to le ni biliọnu meji Naira (2.664bn) wọnu asunwọn ọmọọṣẹ rẹ, Ubua. Ninu owo yii ni wọn lo ti ra ipin idokooowo First Bank to to miliọnu lọna ọgọrun-un Naira (100m).

Awọn aṣiri yii lo jẹ ki NDLEA kọ lẹta si minisita feto idajọ pe ki wọn fun awọn laaye ki awọn gbeṣẹ le gbogbo dukia ati awọn ohun ini mi-in to jẹ ti Kyari.

Lara awọn dukia ti ajọ NDLEA n beere lati gbẹsẹ le ni awọn owo to wa ni akaunti rẹ, ọkọ, awọn ile igbalode ti wọn n pe ni Esteeti, awọn ileetura nla nla, awọn ile gbigbe ati eyi to kọ fun tita tabi to fi rẹnti, aago ọwọ atawọn nnkan olowo iyebiye bẹẹ.  

ALAROYE gbọ pe ọsẹ to kọja ni wọn kọwe lati beere fun asẹ yii, iyẹn lẹyin ti wọn gbe Kyari atawọn eeyan rẹ wa si kootu lori ọrọ kokeeni ti wọn ta ninu rẹ.

Ileeṣẹ to n gbogun ti mimu ati tita oogun oloro, NDLEA, lo kọwe si minisita eto idajọ nilẹ wa pe ki wọn gba awọn laaye lati gbẹsẹ le owo ati dukia to jẹ ti Kyari.

Leave a Reply