NDLEA ka awọn to n gbin igbo mọ’nu oko l’Ondo, ni wọn ba ko gbogbo wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun oloro ti tẹ iyawo ile kan, Mary Donejay ninu oko igbo nla kan niluu Ọgbẹṣẹ nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Obinrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ọhun lọwọ awọn agbofinro tẹ nibi toun ati ọrẹkunrin rẹ, Henry Daniel, ti n kore igbo ti wọn gbin lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti oogun oloro nipinlẹ Ondo, pe o le ni sare ilẹ mẹwaa ti awọn ololufẹ meji ọhun fi dako igbo ninu igbo ọba to wa l’Ọgbẹṣẹ.

O ni awọn oniṣowo igbo naa ko ti i kore ju bii kilogiraamu mẹrin aabọ igbo lọ tawọn fi debẹ, tawọn si fi panpẹ ofin gbe Mary, ṣugbọn ọkọ rẹ raaye sa mọ awọn lọwọ.

Nigba ti ALAROYE n fọrọ wa obinrin naa lẹnu wo, o ṣalaye pe ọmọ meji loun ti bi sẹyin fun ọkọ aarọ, ti awọn ọmọ naa si wa ni ikawọ iya rẹ to n ba a tọju wọn.

Mary ni ile ọti kan toun ti n ṣe ọmọ ọdọ niluu Ọba-Ile, loun ati Daniel ti pade, lẹyin osu diẹ ti awọn ti jọ n ṣe wọle wọde lo fọrọ igbeyawo lọ oun.

O ni Daniel jẹwọ foun pe oun ti ṣẹwọn ri, ati pe iṣẹ igbo gbingbin loun yan laayo latigba toun ti jade lẹwọn, Mary ni ṣọọbu itaja nla ti ọkunrin naa ṣeleri lati si fun oun lo mu inu oun dun toun fi gba lati maa ba a ṣiṣẹ lai ro ti ewu to rọ mọ ajọṣepọ naa.

O ni awọn ti gbọ tẹlẹ pe o ṣee ṣe kawọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti oogun oloro waa ka awọn mọ oko lọjọ naa, ati pe idi ree ti Daniel, ọkọ rẹ, fi raaye sa lọ, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ oun nikan nibi to ti n wọna ati sa.

Leave a Reply