NDLEA lawọn n wa Abba Kyari, wọn lọga ọtẹlẹmuyẹ naa n ṣowo egboogi oloro

Faith Adebọla

Adepele lawọn ẹsun ti wọn ka si ẹsẹ DCP Abba Kyari, da bayii o, ọga ọlọpaa naa ko ti i bọ ninu ọkan ti omi-in tun fi n yọju, latari bi ajọ NDLEA ṣe kede lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe awọn n wa olori awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa tẹlẹ ri naa, wọn ni iwadii ti taṣiiri ẹ pe o lọwọ ninu okoowo gbigbe egboogi oloro.

Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi ti i ṣe Agbẹnusọ fun ajọ NDLEA (National Drug Law Enforcement Agency), to n gbogun ti gbigbe, lilo ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, lo ṣi ọrọ naa paya fawọn oniroyin lọjọ kẹrinla, oṣu keji yii, niluu Abuja pe afurasi ọdaran ni Abba Kyari, o si lẹjọ ijẹ lọdọ awọn.

O ṣalaye pe iṣẹ iwadii to lọọrin kan tawọn ṣe laipẹ yii lo gbe orukọ ọga ọlọpaa naa jade, wọn lo wa lara ẹgbẹ awọn kọlọransi ẹda kan to n ṣowo egboogi oloro kiri agbaye.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọdun to kọja ni iwadii kan ti wọn ṣe lorileede Amẹrika nipa gbajugbaja afurasi ọdaran ọmọ Naijiria kan, Ramon Abass, tawọn eeyan mọ si Hushpuppi, ti fi Abba Kyari han pe ọwọ rẹ ko mọ ninu iwa jibiti, ile-ẹjọ orileede Amẹrika si paṣẹ pe ki wọn ṣeto lati gbe e wa s’Amẹrika ko le ṣalaye ara ẹ niwaju adajọ.

Atigba naa ni wọn ti yọ Abass Kyari nipo ọga ọtẹlẹmuyẹ to wa, ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa si gbe igbimọ oluṣẹwadii kalẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i yanju ọrọ naa.

Leave a Reply