Niṣe lo yẹ ki wọn maa ge nnkan ọmọkunrin ẹni to ba fipa baayan lo pọ sọnu-Kuyẹ

Faith Adebọla, Eko

 Ọgọọrọ awọn to sọrọ nibi apero itagbangba tileegbimọ aṣofin Eko gbe kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo fi ẹdun ọkan wọn han lori bi idajọ ododo ṣe n falẹ, ti oju ẹjọ n daru, lori iwa ifipanilopọ nipinlẹ Eko, wọn ni afi kijọba tete wa nnkan ṣe si i.

Gbọngan apero kan ninu ọgba ile aṣofin naa l’Alausa, Ikẹja, leto ọhun ti waye, awọn aṣofin naa lawọn fẹẹ gba ero araalu lori abadofin kan to da lori iwa ifipabanilopọ, iwa ọdaran abẹle, fifooro ẹni lori ọrọ ibalopọ ati awọn ọrọ to jẹ mọ ọn.

Alaaja Onitiri Kuyẹ, mama ẹni aadọrin ọdun kan to sọrọ nibẹ sọ pe ọpọ igba lo maa n ṣe oun ni kayeefi toun ba gbọ iroyin ifipabanilopọ, ati biba ọmọde ṣeṣekuṣe, ṣugbọn alọ ẹjọ lawọn saaba maa n gbọ, awọn ki i ri abọ rẹ. Obinrin naa dabaa pe ki wọn ṣofin lati maa ge nnkan ọmọkunrin ẹni to ba fipa baayan lo pọ sọnu, tabi ki wọn tẹ wọn lọdaa.

Abilekọ Ọnasanya Adeyọsọla ṣaroye pe lọpọ igba lawọn agbofinro ki i jẹ ki ẹsun ifipabanilopọ lọ bo ṣe yẹ ko lọ, paapaa to ba ti jẹ laarin tọkọ-taya, o tun beere pe ki wọn ṣofin lati daabo bo olufisun, tori bawọn eeyan ṣe maa n dunkooko mọ ẹni to ba lọọ fẹjọ sun.

Nigba to n fesi, Olori awọn aṣofin, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, ẹni ti Ọnarebu Wasiu Sanni Eṣhinlokun, ṣoju fun, sọ pe ninu abadofin tuntun yii, iwe akọsilẹ nipa ẹni to ba jẹbi ifipabanilopọ tabi iwa ipa abẹle, ibaa jẹ ọkunrin tabi obinrin, maa wa, awọn araalu si maa lanfaani si iwe naa, fun iṣẹ iwadii, ati lati dojuti awọn to n hu iru iwa buruku yii, ati pe eto ti wa lati gbe igbimọ kan dide to maa tubọ ṣagbatẹru bi iya to tọ ṣe maa jẹ afipabanilopọ, iwadii ati igbẹjọ ko ṣi ni i falẹ bii tatẹyinwa, tori ọrọ naa ti kuro ni ṣereṣere lorileede yii.

Ọrọ to sọ yii ni alaga igbimọ alabẹ-ṣekele lori ọrọ awọn obinrin ati eto leṣẹẹ-lugbẹ, Ọnarebu Mojisọla Alli-Macaulay, to n ṣoju ẹkun idibo Amuwo-Ọdọfin keji, kin lẹyin.

Leave a Reply